SAKARAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Sakaraya pín sí ọ̀nà meji (1) Orí 1-8 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wolii Sakaraya láàrin ẹẹdẹgbẹta ọdún ó lé ogún (520 B.C.) títí di ẹẹdẹgbẹta ọdún ó lé ọdún mejidinlogun, (518 B.C.) kí á tó bí OLUWA wa. Ní ojúran ni OLUWA ti rán wolii yìí níṣẹ́. Ó ríran nípa ìlú Jerusalẹmu, pé ìlú náà yóo pada bọ̀ sípò ati pé wọn yóo tún tẹmpili kọ́, Ọlọrun yóo ya àwọn eniyan rẹ̀ sí mímọ́ ati pé àkókò kan ń bọ̀ tí olùgbàlà yóo dé. (2) Orí 9-14 Àkójọpọ̀ ìran nípa bíbọ̀ olùdáǹdè ati ìdájọ́ ìkẹyìn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
OLUWA ranṣẹ ìkìlọ̀, ó sì sọ nípa ìrètí ọjọ́ iwájú 1:1–8:23
Ìdájọ́ lórí àwọn ará agbègbè Israẹli 9:1-8
Ìtẹ̀síwájú ati alaafia ní ọjọ́ iwájú 9:9–14:21

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAKARAYA Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀