I. Kor 5
5
Paulu Ṣe Ìdájọ́ Lórí Ìwà Ìbàjẹ́
1A nròhin rẹ̀ kalẹ pe, àgbere wà larin nyin, ati irú àgbere ti a kò tilẹ gburo rẹ̀ larin awọn Keferi, pe ẹnikan ninu nyin fẹ aya baba rẹ̀.
2Ẹnyin si nfẹ̀ soke, ẹnyin kò kuku kãnu ki a le mu ẹniti o hu iwa yi kuro larin nyin.
3Nitori lõtọ, bi emi kò ti si lọdọ nyin nipa ti ara, ṣugbọn ti mo wà pẹlu nyin nipa ti ẹmí, mo ti ṣe idajọ ẹniti o hu iwà yi tan, bi ẹnipe mo wà lọdọ nyin.
4Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa,
5Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa.
6Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu?
7Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa.
8Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ.
9Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀:
10Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro.
11Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun.
12Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn?
13Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Kor 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.