I. Sam 24:4-7

I. Sam 24:4-7 YBCV

Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu. O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.