I. Sam 31
31
Ikú Saulu ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀
(I. Kro 10:1-12)
1AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa.
2Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa.
4Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀.
5Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀.
6Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna.
7Nigbati awọn ọkunrin Israeli ti o wà li apa keji afonifoji na, ati awọn ẹniti o wà li apa keji Jordani, ri pe awọn ọkunrin Israeli sa, ati pe Saulu ati awọn ọmọbibi rẹ̀ si kú, nwọn si fi ilu silẹ, nwọn si sa; awọn Filistini si wá, nwọn si joko si ilu wọn.
8O si ṣe, li ọjọ keji, nigbati awọn Filistini de lati bọ́ nkan ti mbẹ lara awọn ti o kú, nwọn si ri pe, Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta ṣubu li oke Gilboa,
9Nwọn si ke ori rẹ̀, nwọn si bọ́ ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ lọ si ilẹ Filistini ka kiri, lati ma sọ ọ nigbangba ni ile oriṣa wọn, ati larin awọn enia.
10Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ si ile Aṣtaroti: nwọn si kàn okú rẹ̀ mọ odi Betṣani.
11Nigbati awọn ara Jabeṣi-Gileadi si gbọ́ eyiti awọn Filistini ṣe si Saulu;
12Gbogbo awọn ọkunrin alagbara si dide, nwọn si fi gbogbo oru na rìn, nwọn si gbe okú Saulu, ati okú awọn ọmọbibi rẹ̀ kuro lara odi Betṣani, nwọn si wá si Jabeṣi, nwọn si sun wọn nibẹ.
13Nwọn si ko egungun wọn, nwọn si sin wọn li abẹ igi kan ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 31: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.