II. Sam Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Samuẹli Keji fara pẹ́ra pẹlu ti Samuẹli Kinni, ìtàn kan náà ni àwọn Ìwé mejeeji sọ. Ibi tí Ìwé Samuẹli Kinni bá ìtàn náà dé kí ó tó parí, ni Ìwé Samuẹli Keji ti bẹ̀rẹ̀. Samuẹli Keji yìí sọ nípa Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba Juda ti ìhà gúsù (orí 1-4) ati ìgbà tí ó jọba lórí gbogbo ilẹ̀ Israẹli pẹlu àwọn ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n wà ní ìhà àríwá (orí 5-24). Ìwé yìí jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ akitiyan tí Dafidi ṣe láti fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, bí ó ṣe ń kojú àwọn ọ̀tá rẹ̀ láàrin orílẹ̀-èdè rẹ̀ ati àwọn ti orílẹ̀-èdè mìíràn. A rí Dafidi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí igbagbọ rẹ̀ jinlẹ̀ tí ó sì ń fi gbogbo ọkàn sin Ọlọrun, ati ẹni tí ó rí ojurere àwọn eniyan rẹ̀. Sibẹsibẹ, a rí Dafidi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò ní amumọra, tí í sì máa ń dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú pupọ láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ṣugbọn nígbàkúùgbà tí Natani, wolii OLUWA, bá fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kàn án, a máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a sì máa gba ìdájọ́ ati ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọrun bá fún un.
Ìgbésí ayé Dafidi ati àṣeyọrí rẹ̀ jọ àwọn eniyan Israẹli lójú, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n panu pọ̀ ní àkókò ìṣòro pé, ninu àwọn ọmọ Dafidi ni àwọn yóo tún ti yan ọba mìíràn tí yóo dàbí rẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Dafidi jọba Juda 1:1—4:12
Dafidi jọba gbogbo ilẹ̀ Israẹli 5:1—24:25
a. Àwọn ọdún tí Dafidi kọ́kọ́ lò lórí oyè 5:1—10:19
b. Dafidi ati Batiṣeba 11:1—12:25
d. Wahala ati ìnira 12:26—20:26
e. Àwọn ọdún tí Dafidi lò kẹ́yìn lórí oyè 21:1—24:25

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀