I. Tes 1

1
Ìkíni
1PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ awọn ara Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba, ati ninu Jesu Kristi Oluwa: Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
Ìdúpẹ́
2Awa ndupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo fun gbogbo nyin, awa nṣe iranti nyin ninu adura wa;
3Li aisimi li awa nranti iṣẹ igbagbọ́ nyin ati lãla ifẹ ati sũru ireti nyin ninu Oluwa wa Jesu Kristi, niwaju Ọlọrun ati Baba wa;
4Nitoripe awa mọ yiyan nyin, ara olufẹ ti Ọlọrun,
5Bi ihinrere wa kò ti wá sọdọ nyin li ọ̀rọ nikan, ṣugbọn li agbara pẹlu, ati ninu Ẹmí Mimọ́, ati ni ọ̀pọlọpọ igbẹkẹle; bi ẹnyin ti mọ̀ irú enia ti awa jẹ́ larin nyin nitori nyin.
6Ẹnyin si di alafarawe wa, ati ti Oluwa, lẹhin ti ẹnyin ti gbà ọ̀rọ na ninu ipọnju ọ̀pọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹmí Mimọ́:
7Ti ẹnyin si jẹ apẹrẹ fun gbogbo awọn ti o gbagbọ́ ni Makedonia ati Akaia.
8Nitori lati ọdọ nyin lọ li ọ̀rọ Oluwa ti dún jade, kì iṣe ni kìki Makedonia ati Akaia nikan, ṣugbọn ni ibi gbogbo ni ìhin igbagbọ́ nyin si Ọlọrun tàn kalẹ; tobẹ̃ ti awa kò ni isọ̀rọ ohunkohun.
9Nitoripe awọn tikarawọn ròhin nipa wa, irú iwọle ti awa ti ni sọdọ nyin, bi ẹnyin si ti yipada si Ọlọrun kuro ninu ère lati mã sìn Ọlọrun alãye ati otitọ;
10Ati lati duro dè Ọmọ rẹ̀ lati ọrun wá, ẹniti o si ji dide kuro ninu okú, ani Jesu na, ẹniti ngbà wa kuro ninu ibinu ti mbọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Tes 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀