II. Kro 31

31
Hesekaya Ṣe Àtúnṣe Ẹ̀sìn
1NJẸ nigbati gbogbo eyi pari, gbogbo Israeli ti a ri nibẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, nwọn si fọ́ awọn ere tũtu, nwọn si bẹ́ igbo òriṣa lulẹ, nwọn si bì ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹ ṣubu, ninu gbogbo Juda ati Benjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi nwọn fi pa gbogbo wọn run patapata. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli yipada, olukuluku si ilẹ-ini rẹ̀ si ilu wọn.
2Hesekiah si yàn ipa awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi nipa ipa wọn, olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ sisun, ati fun ẹbọ-alafia lati ṣiṣẹ, ati lati dupẹ, ati lati ma yìn li ẹnu-ọ̀na ibudo Oluwa.
3Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa.
4Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin.
5Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.
6Ati awọn ọmọ Israeli ati Juda, ti ngbe inu ilu Juda wọnni, awọn pẹlu mu idamẹwa malu ati agutan wá ati idamẹwa gbogbo ohun mimọ́ ti a yà si mimọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kó wọn jọ li òkiti òkiti.
7Li oṣù kẹta, nwọn bẹ̀rẹ si ifi ipilẹ awọn òkiti lelẹ, nwọn si pari rẹ̀ li oṣù keje.
8Nigbati Hesekiah ati awọn ijoye de, ti nwọn si ri òkiti wọnni, nwọn fi ibukún fun Oluwa, ati Israeli enia rẹ̀.
9Hesekiah si bère lọdọ awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi niti òkiti wọnni.
10Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi.
11Nigbana ni Hesekiah paṣẹ lati pèse iyàrá-iṣura ni ile Ọlọrun; nwọn si pèse wọn.
12Nwọn si mu awọn ọrẹ ati idamẹwa ati ohun ti a yà si mimọ́ wọ̀ ile wá nitõtọ: lori eyiti Kononiah, ọmọ Lefi, nṣe olori, Ṣimei arakunrin rẹ̀ si ni igbakeji.
13Ati Jehieli, ati Asasiah, ati Nahati, ati Asaheli, ati Jerimoti, ati Josabadi, ati Elieli, ati Ismakiah, ati Mahati, ati Benaiah, ni awọn alabojuto labẹ ọwọ Kononiah ati Ṣimei arakunrin rẹ̀, nipa aṣẹ Hesekiah ọba, ati Asariah, olori ile Ọlọrun.
14Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ.
15Ati labẹ ọwọ rẹ̀ ni Edeni, ati Miniamini, ati Jeṣua, ati Ṣemaiah, Amariah, ati Ṣekaniah, ninu ilu awọn alufa, lati fun awọn arakunrin wọn li ẹsẹsẹ, li otitọ, bi fun ẹni-nla, bẹ̃ni fun ẹni-kekere.
16Laika awọn ọkunrin, ti a kọ sinu iwe idile, lati ọmọ ọdun mẹta ati jù bẹ̃ lọ, fun olukuluku wọn ti o nwọ̀ inu ile Oluwa lọ, ìwọn tirẹ̀ lojojumọ, fun iṣẹ ìsin wọn, ninu ilana wọn, gẹgẹ bi ipa wọn;
17Ati fun awọn alufa ti a kọ sinu iwe nipa ile baba wọn, ati awọn ọmọ Lefi, lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ, ninu ilana wọn, nipa ipa wọn:
18Ati fun awọn ti a kọ sinu iwe, gbogbo awọn ọmọ kekeke wọn, awọn aya wọn, ati awọn ọmọkunrin wọn, ati awọn ọmọbinrin wọn, ja gbogbo ijọ enia na: nitori ninu otitọ ni nwọn yà ara wọn si mimọ́ ninu iṣẹ mimọ́.
19Ati fun awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ti o wà li oko igberiko ilu wọn ni olukuluku ilu, awọn ọkunrin wà nibẹ, ti a pè li orukọ, lati ma fi fun gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa, ati fun gbogbo awọn ti a kà ni idile idile ninu awọn ọmọ Lefi.
20Bayi ni Hesekiah si ṣe ni gbogbo Juda, o si ṣe eyiti o dara, ti o si tọ́, ti o si ṣe otitọ, niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
21Ati ninu gbogbo iṣẹ ti o bẹ̀rẹ ninu iṣẹ-ìsin ile Ọlọrun, ati ninu ofin, ati ni aṣẹ, lati wá Ọlọrun, o fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe e, o si ṣe rere.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 31: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀