II. Kro 32

32
Asiria Halẹ̀ Mọ́ Jerusalẹmu
(II. A. Ọba 18:13-37; 19:14-19,35-37; Isa 36:1-22; 37:8-38)
1LẸHIN ti a ti ṣe iṣẹ wọnyi lotitọ, Sennakeribu, ọba Assiria, de, o si wọ̀ inu Juda lọ, o si dótì awọn ilu olodi, o si rò lati gbà wọn fun ara rẹ̀.
2Nigbati Hesekiah ri pe Sennakeribu de, ti o fi oju si ati ba Jerusalemu jagun,
3O ba awọn ijoye rẹ̀ ati awọn ọkunrin alagbara rẹ̀ gbìmọ, lati dí omi orisun wọnni, ti mbẹ lẹhin ilu: nwọn si ràn a lọwọ.
4Bẹ̃li ọ̀pọlọpọ enia kojọ pọ̀, awọn ẹniti o dí gbogbo orisun, ati odò ti nṣàn la arin ilẹ na ja, wipe, Nitori kili awọn ọba Assiria yio ṣe wá, ki nwọn ki o si ri omi pupọ̀?
5O mu ara rẹ̀ le pẹlu, o si mọ gbogbo odi ti o ti ya, o si gbé e ga de awọn ile-iṣọ, ati odi miran lode, o si tun Millo ṣe ni ilu Dafidi, o si ṣe ọ̀kọ ati apata li ọ̀pọlọpọ.
6O si yàn awọn balogun lori awọn enia, o si kó wọn jọ pọ̀ sọdọ rẹ̀ ni ita ẹnu-bode ilu, o si sọ̀rọ iyanju fun wọn, wipe,
7Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboya, ẹ má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò nyin nitori ọba Assiria, tabi nitori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀; nitori awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rẹ̀ lọ:
8Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda.
9Lẹhin eyi ni Sennakeribu, ọba Assiria, rán awọn iranṣẹ si Jerusalemu, (ṣugbọn on tikararẹ̀ dótì Lakiṣi ati gbogbo ogun rẹ̀ pẹlu rẹ̀) sọdọ Hesekiah, ọba Juda ati sọdọ gbogbo Juda ti o wà ni Jerusalemu wipe,
10Bayi ni Sennakeribu, ọba Assiria, wi pe, Kili ẹnyin gbẹkẹle, ti ẹnyin joko ninu odi agbara ni Jerusalemu?
11Kò ṣepe Hesekiah ntàn nyin lati fi ara nyin fun ikú, nipa ìyan, ati nipa ongbẹ, o nwipe, Oluwa, Ọlọrun wa, yio gbà wa lọwọ ọba Assiria?
12Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀?
13Enyin kò ha mọ̀ ohun ti emi ati awọn baba mi ti ṣe si gbogbo enia ilẹ miran? awọn oriṣa awọn orilẹ-ède ilẹ wọnni ha le gbà ilẹ wọn lọwọ mi rara?
14Tani ninu gbogbo awọn oriṣa orilẹ-ède wọnni, ti awọn baba mi parun tũtu, ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ti Ọlọrun nyin yio fi le gbà nyin lọwọ mi?
15Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o tàn nyin jẹ, bẹ̃ni ki o máṣe rọ̀ nyin bi iru eyi, bẹ̃ni ki ẹ máṣe gbà a gbọ́: nitoriti kò si oriṣa orilẹ-ède tabi ijọba kan ti o le gbà enia rẹ̀ lọwọ mi, ati lọwọ awọn baba mi: ambọtori Ọlọrun nyin ti yio fi gbà nyin lọwọ mi?
16Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ jù bẹ̃ lọ si Oluwa Ọlọrun, ati si iranṣẹ rẹ̀, Hesekiah.
17O kọ iwe pẹlu lati kẹgan Oluwa, Ọlọrun Israeli, ati lati sọ̀rọ òdi si i, wipe, Gẹgẹ bi awọn oriṣa orilẹ-ède ilẹ miran kò ti gbà awọn enia wọn lọwọ mi, bẹ̃li Ọlọrun Hesekiah kì yio gbà awọn enia rẹ̀ lọwọ mi.
18Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara li ède Juda si awọn enia Jerusalemu ti mbẹ lori odi, lati dẹruba wọn, ati lati dãmu wọn; ki nwọn ki o le kó ilu na.
19Nwọn si sọ̀rọ òdi si Ọlọrun Jerusalemu, bi ẹnipe si awọn oriṣa enia ilẹ aiye, ti iṣe iṣẹ ọwọ enia.
20Ati nitori eyi ni Hesekiah, ọba, ati Isaiah woli, ọmọ Amosi, gbadura, nwọn si kigbe si ọrun.
21Oluwa si rán Angeli kan, ẹniti o pa gbogbo awọn alagbara ogun, ati awọn aṣãju, ati awọn balogun ni ibudo ọba Assiria. Bẹ̃li o fi itiju pada si ilẹ on tikararẹ̀. Nigbati o si wá sinu ile oriṣa rẹ̀, awọn ti o ti inu ara rẹ̀ jade si fi idà pa a nibẹ.
22Bayi li Oluwa gbà Hesekiah ati awọn ti ngbe Jerusalemu lọwọ Sennakeribu ọba Assiria, ati lọwọ gbogbo awọn omiran, o si ṣọ́ wọn ni iha gbogbo.
23Ọ̀pọlọpọ si mu ẹ̀bun fun Oluwa wá si Jerusalemu, ati ọrẹ fun Hesekiah, ọba Juda: a si gbé e ga loju gbogbo orilẹ-ède lẹhin na.
Àìsàn ati Ìgbéraga Hesekaya
(II. A. Ọba 20:1-3,12-19; Isa 38:1-3; 39:1-8)
24Li ọjọ wọnni, Hesekiah ṣe aisan de oju ikú, o si gbadura si Oluwa; O si da a lohùn, O si fi àmi kan fun u.
25Ṣugbọn Hesekiah kò si tun pada san gẹgẹ bi ore ti a ṣe fun u: nitoriti ọkàn rẹ̀ gbega: nitorina ni ibinu ṣe wà lori rẹ̀, lori Juda, ati lori Jerusalemu.
26Ṣugbọn Hesekiah rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, niti igberaga ọkàn rẹ̀, ati on ati awọn ti ngbe Jerusalemu, bẹ̃ni ibinu Oluwa kò wá sori wọn li ọjọ Hesekiah.
Ọrọ̀ ati Ògo Hesekaya
27Hesekiah si li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ ati ọlá: o si ṣe ibi-iṣura fun ara rẹ̀ fun fadakà, ati fun wura, ati fun okuta iyebiye, ati fun turari ati fun apata, ati fun oniruru ohun-elo iyebiye.
28Ile-iṣura pẹlu fun ibisi ọkà, ati ọti-waini; ati ororo; ati ile fun gbogbo oniruru ẹran, ati ọgbà fun agbo-ẹran.
29Pẹlupẹlu o ṣe ilu fun ara rẹ̀, ati agbo agutan ati agbo malu li ọ̀pọlọpọ: nitoriti Ọlọrun fun u li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ.
30Hesekiah kanna yi li o dí ipa-omi ti o wà li òke Gihoni pẹlu, o si mu u wá isalẹ tara si iha iwọ-õrun ilu Dafidi. Hesekiah si ṣe rere ni gbogbo iṣẹ rẹ̀.
31Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Hesekaya
(II. A. Ọba 20:20-21)
32Ati iyokù iṣe Hesekiah ati iṣẹ rere rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe iran Isaiah woli, ọmọ Amosi, ani ninu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.
33Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sin i ninu iboji awọn ọmọ Dafidi: ati gbogbo Juda ati awọn ti ngbe Jerusalemu ṣe ẹyẹ fun u ni iku rẹ̀. Manasse ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 32: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀