II. Tes Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ lórí àìmọ ìgbà gan-an tí Kristi ń pada bọ̀ dá rúdurùdu sílẹ̀ ninu ìjọ Tẹsalonika. Nígbà tí rúdurùdu yìí kò lójú, ni Paulu fi kọ Ìwé Keji sí Àwọn Ará Tẹsalonika. Kókó ohun tí ó ṣe àlàyé lé lórí ni sísọ tí àwọn kan ń sọ pé àkókò ìpadàbọ̀ Oluwa ti dé. Paulu ní kì í ṣe bí wọ́n ti ń wí ni ọ̀rọ̀ rí. Ó ṣe àlàyé pé kí Kristi tó pada wá, ibi ati ìwà burúkú gbọdọ̀ kọ́ pọ̀ dé góńgó ná. Ẹ̀dá kan tí Paulu pè ní “Ẹni ibi” ni ó sọ pé yóo ṣe alákòóso gbogbo ìwà ibi ati ìwà burúkú àkókò tí à ń wí yìí.
Aposteli yìí tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pataki pé kí àwọn olùka ìwé rẹ̀ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ wọn, láì wo ti ìyọnu ati ìjìyà tí wọn yóo máa rí, kí wọn máa fi ọwọ́ wọn ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn bí Paulu ati àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ ti ń ṣe, kí wọ́n sì máa ní ìfaradà ninu iṣẹ́ rere.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju 1:1-2
Fífi ìmọrírì hàn ati ìyìn 1:3-12
Ẹ̀kọ́ nípa ìpadàbọ̀ Kristi 2:1-17
Ọ̀rọ̀ ìyànjú nípa ìhùwàsí onigbagbọ 3:1-15
Ọ̀rọ̀ ìparí 3:16-18

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Tes Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀