Iṣe Apo 11:19-26

Iṣe Apo 11:19-26 YBCV

Nitorina awọn ti a si tuka kiri niti inunibini ti o ṣẹ̀ niti Stefanu, nwọn rìn titi de Fenike, ati Kipru, ati Antioku, nwọn kò sọ ọ̀rọ na fun ẹnikan, bikoṣe fun kìki awọn Ju. Ṣugbọn awọn kan mbẹ ninu wọn ti iṣe ara Kipru, ati Kirene; nigbati nwọn de Antioku nwọn sọ̀rọ fun awọn Hellene pẹlu, nwọn nwasu Jesu Oluwa. Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu wọn: ọpọlọpọ awọn ti o gbagbọ́ yipada si Oluwa. Ihìn wọn si de etí ijọ ti o wà ni Jerusalemu: nwọn si rán Barnaba lọ titi de Antioku; Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa. Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa. Barnaba si jade lọ si Tarsu lati wá Saulu. Nigbati o si ri i, o mu u wá si Antioku. O si ṣe, fun ọdun kan gbako ni nwọn fi mba ijọ pejọ pọ̀, ti nwọn si kọ́ enia pipọ. Ni Antioku li a si kọ́ pè awọn ọmọ-ẹhin ni Kristian.