Ìṣe àwọn Aposteli 11:19-26

Ìṣe àwọn Aposteli 11:19-26 YCB

Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa. Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa. Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”