Est 8

8
Wọ́n fún Àwọn Juu Láṣẹ láti Bá Àwọn Ọ̀tá Wọn Jà
1Ni ijọ na ni Ahaswerusi ọba fi ile Hamani ọta awọn Ju, jìn Esteri, ayaba; Mordekai si wá siwaju ọba; nitori Esteri ti sọ bi o ti ri si on.
2Ọba si bọ́ oruka rẹ̀, ti o ti gbà lọwọ Hamani, o si fi i fun Mordekai. Esteri si fi Mordekai ṣe olori ile Hamani.
3Esteri si tun sọ niwaju ọba, o wolẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀, o si fi omijé bẹ̀ ẹ pe, ki o mu buburu Hamani, ara Agagi kuro, ati ete ti o ti pa si awọn Ju.
4Nigbana ni ọba nà ọpá-alade wura si Esteri. Bẹ̃ni Esteri dide, o si duro niwaju ọba.
5O si wi pe, bi o ba wù ọba, bi mo ba si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀, ti nkan na ba si tọ́ loju ọba, bi mo ba si wù ọba, jẹ ki a kọwe lati yí iwe ete Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi nì pada, ti o ti kọ lati pa awọn Ju run, ti o wà ni gbogbo ìgberiko ọba.
6Nitori pe, emi ti ṣe le ri ibi ti yio wá ba awọn enia mi? tabi emi ti ṣe le ri iparun awọn ibatan mi?
7Nigbana ni Ahaswerusi ọba wi fun Esteri ayaba, ati fun Mordekai ara Juda na pe, Sa wò o, emi ti fi ile Hamani fun Esteri; on ni nwọn si ti so rọ̀ lori igi, nitoripe o ti gbe ọwọ le awọn Ju.
8Ẹnyin kọwe ẹ̀wẹ li orukọ ọba, nitori awọn Ju bi ẹnyin ti fẹ́, ki ẹ si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀: nitori iwe ti a ba fi orukọ ọba kọ, ti a ba si fi òruka ọba ṣe edidi, ẹnikan kò le yi i pada.
9Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn.
10Orukọ Ahaswerusi ọba li a fi kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀; o si fi iwe wọnni rán awọn ojiṣẹ lori ẹṣin, ti o gùn ẹṣin yiyara, ani ibãka, ọmọ awọn abo ẹṣin.
11Ninu eyiti ọba fi aṣẹ fun gbogbo awọn Ju, ti o wà ni ilu gbogbo, lati kó ara wọn jọ, ati lati duro gbà ẹmi ara wọn là, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo agbara awọn enia, ati ìgberiko na, ti o ba fẹ kọlu wọn, pẹlu awọn ọmọ wẹwẹ ati awọn obinrin ki o ṣegbe; ki nwọn ki o si kó ìni wọn fun ara wọn,
12Li ọjọ kanṣoṣo ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, li ọjọ kẹtala, oṣù kejila ti iṣe oṣù Adari.
13Ọ̀ran inu iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo ìgberiko lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki awọn Ju ki o le mura de ọjọ na, lati gbẹsan ara wọn lara awọn ọta wọn.
14Bẹ̃ni awọn ojiṣẹ́ ti nwọn gun ẹṣin yiyara ati ibãka jade lọ, nitori aṣẹ ọba, nwọn yara, nwọn sare. A si pa aṣẹ yi ni Ṣuṣani ãfin.
15Mordekai si jade kuro niwaju ọba, ninu aṣọ ọba, alaro ati funfun, ati ade wura nla, ati ẹ̀wu okùn ọ̀gbọ kikuná, ati elese aluko; ayọ̀ ati inu didùn si wà ni ilu Ṣuṣani.
16Awọn Ju si ni imọlẹ, ati inu didùn, ati ayọ̀ ati ọlá.
17Ati ni olukulùku ìgberiko, ati ni olukuluku ilu nibikibi ti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, awọn Ju ni ayọ̀ ati inu-didùn, àse, ati ọjọ rere. Ọ̀pọlọpọ awọn enia ilẹ na si di enia Juda; nitori ẹ̀ru awọn Ju ba wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Est 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀