Est 9
9
Àwọn Juu Pa Àwọn Ọ̀tá Wọn Run
1Njẹ li oṣù kejila, eyini ni oṣù Adari, li ọjọ kẹtala rẹ̀, ti ofin ọba ati aṣẹ rẹ̀ sunmọle lati mu u ṣẹ, li ọjọ ti awọn ọta awọn Ju ti rò pe, awọn o bori wọn, (bi o tilẹ ti jẹ pe, ati yi i pada pe, ki awọn Ju ki o bori awọn ti o korira wọn;)
2Awọn Ju kó ara wọn jọ ninu ilu wọn ninu gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, lati gbe ọwọ le iru awọn ti o nwá ifarapa wọn: ẹnikẹni kò si le kò wọn loju; nitori ẹ̀ru wọn bà gbogbo enia.
3Gbogbo awọn olori ìgberiko, ati awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati awọn ti nṣe iṣẹ ọba, ràn awọn Ju lọwọ, nitori ẹ̀ru Mordekai bà wọn.
4Nitori Mordekai tobi ni ile ọba, okiki rẹ̀ si kàn ja gbogbo ìgberiko: nitori ọkunrin yi Mordekai ntobi siwaju ati siwaju.
5Bayi ni awọn Ju a fi idà ṣá gbogbo awọn ọta wọn pa, ni pipa ati piparun, nwọn si ṣe awọn ọta ti o korira wọn bi nwọn ti fẹ.
6Ati ni Ṣuṣani ãfin awọn Ju pa ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin run.
7Ati Farṣandata, ati Dalfoni, ati Aspata,
8Ati Porata, ati Adalia, ati Aridata,
9Ati Farmaṣta, ati Arisai, ati Aridai, ati Faisata,
10Awọn ọmọ Hamani, ọmọ Medata, mẹwẹwa, ọta awọn Ju ni nwọn pa; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.
11Li ọjọ na a mu iye awọn ti a pa ni Ṣuṣani ãfin wá siwaju ọba.
12Ọba si wi fun Esteri ayaba pe, Awọn Ju pa, nwọn si ti pa ẹ̃dẹgbẹta enia run ni Ṣuṣani ãfin, ati awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa: kini nwọn ha ṣe ni gbogbo ìgberiko ọba iyokù? nisisiyi kini ẹbẹ rẹ? a o si fi fun ọ tabi kini iwọ o si tun bère si i? a o si ṣe e.
13Nigbana ni Esteri wipe, Bi o ba wù ọba, jẹ ki a fi aṣẹ fun awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani ki nwọn ki o ṣe li ọ̀la pẹlu gẹgẹ bi aṣẹ ti oni, ki a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀ lori igi.
14Ọba si paṣẹ pe, ki a ṣe bẹ̃; a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani; a si so awọn ọmọ Hamani mẹwẹwa rọ̀.
15Nitorina awọn Ju ti o wà ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹrinla oṣù Adari pẹlu, nwọn si pa ọ̃durun ọkunrin ni Ṣuṣani; ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kàn nkan wọn.
16Ṣugbọn awọn Ju miran, ti o wà ni ìgberiko ọba, kó ara wọn jọ, nwọn dide duro lati gbà ẹmi ara wọn là, nwọn si simi kuro lọwọ awọn ọta wọn, nwọn si pa ẹgbã mẹtadilogoji enia o le ẹgbẹrin ninu awọn ọta wọn, ṣugbọn nwọn kò fi ọwọ kan nkan wọn.
17Li ọjọ kẹtala oṣù Adari, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀ ni nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati ayọ̀.
18Ṣugbọn awọn Ju ti mbẹ ni Ṣuṣani kó ara wọn jọ li ọjọ kẹtala rẹ̀, ati li ọjọ kẹrinla rẹ̀; ati li ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ nwọn simi, nwọn si ṣe e li ọjọ àse ati inu didùn.
19Nitorina awọn Ju ti o wà ni iletò wọnni, ti nwọn ngbe ilu ti kò li odi, nwọn ṣe ọjọ kẹrinla oṣù Adari li ọjọ inu-didùn, ati àse, ati ọjọ rere, ati ọjọ ti olukulùku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀.
20Mordekai si kọwe nkan wọnyi, o si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba, si awọn ti o sunmọ etile, ati awọn ti o jina.
21Lati fi eyi lelẹ larin wọn, ki nwọn ki o le ma pa ọjọ kẹrinla oṣù Adari, ati ọjọ kẹ̃dogun rẹ̀ mọ́ li ọdọdun.
22Bi ọjọ lọwọ eyiti awọn Ju simi kuro ninu awọn ọta wọn, ati oṣù ti a sọ ibanujẹ wọn di ayọ̀, ati ọjọ ọ̀fọ di ọjọ rere; ki nwọn ki o le sọ wọn di ọjọ àse, ati ayọ̀, ati ọjọ ti olukuluku nfi ipin onjẹ ranṣẹ si ẹnikeji rẹ̀, ati ẹbun fun awọn talaka.
23Awọn Ju si gbà lati ṣe bi nwọn ti bẹ̀rẹ si iṣe, ati bi Mordekai si ti kọwe si wọn.
24Pe, Hamani ọmọ Medata, ara Agagi nì, ọta gbogbo awọn Ju ti gbiro lati pa awọn Ju run, o si ti da Puri, eyinì ni ibo, lati pa wọn, ati lati run wọn;
25Ṣugbọn nigbati Esteri tọ̀ ọba wá, o fi iwe paṣẹ pe, ki ete buburu ti a ti pa si awọn Ju ki o le pada si ori on tikalarẹ̀, ati ki a so ati on ati awọn ọmọ rẹ̀ rọ̀ sori igi.
26Nitorina ni nwọn ṣe npè ọjọ wọnni ni Purimu bi orukọ Puri. Nitorina gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ inu iwe yi, ati nitori gbogbo eyi ti oju wọn ti ri nitori ọ̀ran yi, ati eyiti o ti ba wọn,
27Awọn Ju lanà rẹ̀, nwọn si gbà a kanri wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ati fun gbogbo awọn ti o dà ara wọn pọ̀ mọ wọn, pe ki o máṣe yẹ̀, ki nwọn ki o ma pa ọjọ mejeji wọnyi mọ́ gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi akokò wọn ti a yàn lọdọdun.
28Ati pe, ki nwọn ma ranti ọjọ wọnyi, ki nwọn si ma kiyesi i ni irandiran wọn gbogbo; olukuluku idile, olukuluku ìgberiko, ati olukuluku ilu; ati pe, ki Purimu wọnyi ki o máṣe yẹ̀ larin awọn Ju, tabi ki iranti wọn ki o máṣe parun ninu iru-ọmọ wọn.
29Nigbana ni Esteri ayaba, ọmọbinrin Abihaili, ati Mordekai, ara Juda, fi ọlá gbogbo kọwe, lati fi idi iwe keji ti Purimu yi mulẹ.
30O si fi iwe ranṣẹ si gbogbo awọn Ju, si ẹtadilãdoje ìgberiko ijọba Ahaswerusi, ọ̀rọ alafia ati otitọ.
31Lati fi idi ọjọ Purimu wọnyi mulẹ, li akokò wọn ti a yàn gẹgẹ bi Mordekai, ara Juda, ati Esteri ayaba ti paṣẹ fun wọn, ati bi nwọn ti pinnu rẹ̀ fun ara wọn, ati fun iru-ọmọ wọn, ọ̀ran ãwẹ ati ẹkún wọn.
32Aṣẹ Esteri si fi idi ọ̀ran Purimu yi mulẹ; a si kọ ọ sinu iwe.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Est 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.