Gẹn 28

28
1ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani.
2Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ.
3Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia.
4Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu.
5Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.
Esau Fẹ́ Aya Mìíràn
6Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani;
7Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu:
8Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;
9Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.
Àlá Jakọbu ní Bẹtẹli
10Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani.
11O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na.
12O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
13Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.
14Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.
15Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.
16Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀.
17Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun.
18Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀.
19O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri.
20Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora,
21Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi.
22Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 28: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀