Gẹn 29

29
Jakọbu Dé sí Ilé Labani
1JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn.
2O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na.
3Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀.
4Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá.
5O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ.
6O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran.
7O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn.
8Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi.
9Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn.
10O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀.
11Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
12Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀.
13O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani.
14Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.
Jakọbu Sin Labani nítorí Rakẹli ati Lea
15Labani si wi fun Jakobu pe, Iwọ o ha ma sìn mi li asan bi, nitoriti iwọ iṣe arakunrin mi? elo li owo iṣẹ rẹ, wi fun mi?
16Labani si ni ọmọbinrin meji: orukọ ẹgbọ́n a ma jẹ Lea, orukọ aburo a si ma jẹ Rakeli.
17Oju Lea kò li ẹwà, ṣugbọn Rakeli ṣe arẹwà, o si wù ni.
18Jakobu si fẹ́ Rakeli; o si wipe, Emi o sìn ọ li ọdún meje nitori Rakeli, ọmọbinrin rẹ abikẹhin.
19Labani si wipe, O san lati fi i fun ọ, jù ki nfi i fun ẹlomiran lọ: ba mi joko.
20Jakobu si sìn i li ọdún meje fun Rakeli; nwọn sì dabi ijọ́ melokan li oju rẹ̀ nitori ifẹ́ ti o fẹ́ ẹ.
21Jakobu si wi fun Labani pe, Fi aya mi fun mi, nitoriti ọjọ́ mi pé, ki emi ki o le wọle tọ̀ ọ.
22Labani si pè gbogbo awọn enia ibẹ̀ jọ, o si se àse.
23O si ṣe li alẹ, o mú Lea ọmọbinrin rẹ̀, o sìn i tọ̀ ọ wá; on si wọle tọ̀ ọ lọ.
24Labani si fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fun Lea, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀.
25O si ṣe, li owurọ, wò o, o jẹ́ Lea: o si wi fun Labani pe, Ẽwo li eyiti iwọ ṣe si mi yi? nitori Rakeli ki mo ṣe sìn ọ, njẹ ẽhatiṣe ti o fi ṣe erú si mi?
26Labani si wi fun u pe, A kò gbọdọ ṣe bẹ̃ ni ilẹ wa, lati sìn aburo ṣaju ẹgbọ́n.
27Ṣe ọ̀sẹ ti eleyi pé, awa o si fi eyi fun ọ pẹlu, nitori ìsin ti iwọ o sìn mi li ọdún meje miran si i.
28Jakobu si ṣe bẹ̃, o si ṣe ọ̀sẹ rẹ̀ pé: o si fi Rakeli ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya pẹlu.
29Labani si fi Bilha, ọmọbinrin ọdọ rẹ̀, fun Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀, ni iranṣẹ rẹ̀.
30O si wọle tọ̀ Rakeli pẹlu, o si fẹ́ Rakeli jù Lea lọ, o si sìn i li ọdún meje miran si i.
Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Bí fún Jakọbu
31Nigbati OLUWA si ri i pe a korira Lea, o ṣi i ni inu: ṣugbọn Rakeli yàgan.
32Lea si loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Reubeni: nitori ti o wipe, OLUWA wò ìya mi nitõtọ: njẹ nitorina, ọkọ mi yio fẹ́ mi.
33O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Nitori ti OLUWA ti gbọ́ pe a korira mi, nitorina li o ṣe fun mi li ọmọ yi pẹlu: o si sọ orukọ rẹ̀ ni Simeoni.
34O si tun loyun, o si bí ọmọkunrin kan; o si wipe, Njẹ nigbayi li ọkọ mi yio faramọ́ mi, nitori ti mo bí ọmọkunrin mẹta fun u: nitorina li o ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Lefi.
35O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan: o si wipe, Nigbayi li emi o yìn OLUWA: nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Judah; o si dẹkun bíbi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 29: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀