Isa 50

50
1BAYI ni Oluwa wi, Nibo ni iwe ikọsilẹ iyá nyin gbe wà, ẹniti mo ti kọ̀ silẹ? tabi tani ninu awọn onigbese mi ti mo ti tà nyin fun? Kiyesi i, nitori aiṣedẽde nyin li ẹnyin ti tà ara nyin, ati nitori irekọja nyin li a ṣe kọ̀ iyá nyin silẹ.
2Nitori nigbati mo de, kò si ẹnikan? nigbati mo pè, kò si ẹnikan lati dahùn? Ọwọ́ mi ha kuru tobẹ̃ ti kò fi le rapada? tabi emi kò ha li agbara lati gbani? Kiyesi i, ni ibawi mi mo gbẹ okun, mo sọ odò nla di aginjù, ẹja wọn nrùn nitori ti omi kò si, nwọn si kú fun ongbẹ.
3Mo fi ohun dúdu wọ̀ awọn ọrun, mo si fi aṣọ ọfọ̀ ṣe ibora wọn.
Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA
4Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ.
5Oluwa Jehofa ti ṣí mi li eti, emi kò si ṣe aigbọràn, bẹ̃ni emi kò yipada.
6Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si.
7Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi.
8Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi.
9Kiye si i, Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ, tani o dá mi li ẹbi? wò o, gbogbo wọn o di ogbó bi ẹwù; kokòro yio jẹ wọn run.
10Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀.
11Kiye si i, gbogbo ẹnyin ti o dá iná, ti ẹ fi ẹta iná yi ara nyin ká: ẹ mã rìn ninu imọlẹ iná nyin, ati ninu ẹta iná ti ẹ ti dá. Eyi ni yio jẹ ti nyin lati ọwọ́ mi wá; ẹnyin o dubulẹ ninu irora.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 50: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀