Isa 51
51
Ọ̀rọ̀ Ìtùnú fún Jerusalẹmu
1GBỌ ti emi, ẹnyin ti ntẹle ododo, ẹnyin ti nwá Oluwa; wò apáta nì ninu eyiti a ti gbẹ́ nyin, ati ihò kòto nì nibiti a gbe ti wà nyin.
2Ẹ wò Abrahamu baba nyin, ati Sara ti o bi nyin; nitori on nikan ni mo pè, mo si sure fun u, mo si mu u pọ̀ si i.
3Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin.
4Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia.
5Ododo mi wà nitosí; igbala mi ti jade lọ, apá mi yio si ṣe idajọ awọn enia; awọn erekùṣu yio duro dè mi, apá mi ni nwọn o si gbẹkẹle.
6Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́.
7Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn.
8Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran.
9Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́?
10Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja?
11Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.
12Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.
13Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà?
14Ondè ti a ti ṣí nipo yara ki a ba le tú u silẹ, ati ki o má ba kú sinu ihò, tabi ki onjẹ rẹ̀ má ba tán.
15Ṣugbọn emi Oluwa Ọlọrun rẹ ti o pin okun ni iyà, eyi ti ìgbi rẹ̀ nhó; Oluwa awọn ọmọ-ogun ni orukọ rẹ̀.
16Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi.
Òpin Ìjìyà Jerusalẹmu
17Ji, ji, dide duro, iwọ Jerusalemu, ti o ti mu li ọwọ́ Oluwa ago irúnu rẹ̀; iwọ ti mu gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago ìwarìri, iwọ si fọ́n wọn jade.
18Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba.
19Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu?
20Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ.
21Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini:
22Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ.
23Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 51: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.