Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi.
O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.
O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, nigbati iwọ wà li ọdọmọde, iwọ a ma di ara rẹ li àmurè, iwọ a si ma rìn lọ si ibiti iwọ ba fẹ: ṣugbọn nigbati iwọ ba di arugbo, iwọ o nà ọwọ́ rẹ jade, ẹlomiran yio si di ọ li amure, yio si mu ọ lọ si ibiti iwọ kò fẹ.
O wi eyi, o fi nṣapẹrẹ irú ikú ti yio fi yìn Ọlọrun logo. Lẹhin igbati o si ti wi eyi tan, o wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.