JESU si wọ̀ Jeriko lọ, o si nkọja lãrin rẹ̀.
Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ti a npè ni Sakeu, o si jẹ olori agbowode kan, o si jẹ ọlọrọ̀.
O si nfẹ lati ri ẹniti Jesu iṣe; kò si le ri i, nitori ọ̀pọ enia, ati nitoriti on ṣe enia kukuru.
O si sure siwaju, o gùn ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitoriti yio kọja lọ niha ibẹ̀.
Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.
O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a.
Nigbati nwọn si ri i, gbogbo wọn nkùn, wipe, O lọ iwọ̀ lọdọ ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ.
Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.
Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.
Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.