Filp 2

2
Jesu Rẹ Ara Rẹ̀ Sílẹ̀
1NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà,
2Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan.
3Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.
4Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.
5Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu:
6Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba:
7Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia.
8Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu.
9Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ:
10Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ;
11Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.
Onigbagbọ Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ ninu Ayé
12Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì iṣe nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, ṣugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã ṣiṣẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri,
13Nitoripe Ọlọrun ni nṣiṣẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀.
14Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan.
15Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye;
16Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan.
17Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu.
18Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.
Timotiu ati Epafiroditu
19Ṣugbọn mo ni ireti ninu Jesu Oluwa, lati rán Timotiu si nyin ni lọ̃lọ yi, ki emi pẹlu le ni ifọkanbalẹ nigbati mo ba gburó ijoko nyin.
20Nitori emi kò ni ẹni oninu kanna ti o dabi rẹ̀, ti yio ma fi tinutinu ṣe aniyan nyin.
21Nitori gbogbo wọn ni ntọju nkan ti ara wọn, kì iṣe nkan ti iṣe ti Jesu Kristi.
22Ṣugbọn ẹnyin ti mọ̀ ọ dajudaju, pe gẹgẹ bi ọmọ lọdọ baba rẹ̀, bẹ̃li o si ti mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere.
23Nitorina on ni mo ni ireti lati rán si nyin nisisiyi, nigbati mo ba woye bi yio ti ri fun mi.
24Ṣugbọn mo gbẹkẹle Oluwa, pe emi tikarami pẹlu yio wá ni lọ̃lọ.
25Mo ka a si pe n ko le ṣairan Epafroditu arakunrin mi si nyin, ati olubaṣiṣẹ mi ati ọmọ-ogun ẹgbẹ mi, ṣugbọn iranṣẹ nyin, ati ẹniti nṣe iranṣẹ fun mi ninu aini mi.
26Nitoriti ọkàn rẹ̀ fà si gbogbo nyin, o si kún fun ibanujẹ, nitoriti ẹnyin ti gbọ́ pe on ti ṣe aisan.
27Nitõtọ li o ti ṣe aisan titi de oju ikú: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣãnu fun u; kì si iṣe fun on nikan, ṣugbọn fun mi pẹlu, ki emi ki o màṣe ni ibanujẹ lori ibanujẹ.
28Nitorina ni mo ṣe fi titara-titara rán a, pe nigbati ẹnyin ba si tún ri i, ki ẹnyin ki o le yọ̀, ati ki ibanujẹ mi ki o le dínkù.
29Nitorina ẹ fi ayọ̀ pupọ gbà a nipa ti Oluwa; ki ẹ si ma bù ọlá fun irú awọn ẹni bẹ̃:
30Nitoripe nitori iṣẹ Kristi li o ṣe sunmọ ẹnu-ọ̀na ikú, ti kò si kà ẹmí ara rẹ̀ si, lati mu aitó iṣẹ isin nyin si mi kun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Filp 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀