Filp 3
3
Òdodo Tòótọ́
1LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu.
2Ẹ kiyesara lọdọ awọn ajá, ẹ kiyesara lọdọ awọn oniṣẹ-buburu, ẹ kiyesara lọdọ awọn onilà.
3Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara;
4Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju:
5Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi;
6Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.
7Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi.
8Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi,
9Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́:
10Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀;
11Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú.
Ète tí Ó Ga Jù lọ
12Kì iṣe pe ọwọ mi ti tẹ ẹ na, tabi mo ti di pipé: ṣugbọn emi nlepa nṣo, bi ọwọ́ mi yio le tẹ̀ ère na, nitori eyiti a ti di mi mu pẹlu, lati ọdọ Kristi Jesu wá.
13Ará emi kò kà ara mi si ẹniti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ na: ṣugbọn ohun kan yi li emi nṣe, emi ngbagbé awọn nkan ti o wà lẹhin, mo si nnàgà wò awọn nkan ti o wà niwaju,
14Emi nlepa lati de opin ire-ije nì fun ère ìpe giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu.
15Nitorina, ẹ jẹ ki iye awa ti iṣe ẹni pipé ni ero yi: bi ẹnyin bá si ni ero miran ninu ohunkohun, eyi na pẹlu ni Ọlọrun yio fi hàn nyin.
16Kiki pe, ibiti a ti de na, ẹ jẹ ki a mã rìn li oju ọna kanna, ki a ni ero kanna.
17Ará, ẹ jumọ ṣe afarawe mi, ẹ si ṣe akiyesi awọn ti nrìn bẹ̃, ani bi ẹ ti ni wa fun apẹrẹ.
18(Nitori ọ̀pọlọpọ ni nrìn, nipasẹ awọn ẹniti mo ti nwi fun nyin nigbakugba, ani, ti mo si nsọkun bi mo ti nwi fun nyin nisisiyi, pe, ọtá agbelebu Kristi ni nwọn:
19Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.)
20Nitori ilu-ibilẹ wa mbẹ li ọrun: lati ibiti awa pẹlu gbé nfojusọna fun Olugbala, Jesu Kristi Oluwa:
21Ẹniti yio sọ ara irẹlẹ wa di ọ̀tun ki o le bá ara ogo rẹ̀ mu, gẹgẹ bi iṣẹ-agbara nipasẹ eyiti on le fi tẹ ori ohun gbogbo ba fun ara rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Filp 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.