Owe 23
23
1NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi.
2Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia.
3Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni.
4Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ.
5Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun.
6Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀.
7Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ.
8Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù.
9Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ.
10Máṣe ṣi àla atijọ; má si ṣe bọ sinu oko alaini-baba.
11Nitoripe Olurapada wọn lagbara; yio gbà ìja wọn ja ti awọn tirẹ.
12Fi aiya si ẹkọ́, ati eti rẹ si ọ̀rọ ìmọ.
13Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú.
14Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi.
15Ọmọ mi, bi ọkàn rẹ ba gbọ́n ọkàn mi yio yọ̀, ani emi pẹlu.
16Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ.
17Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.
18Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.
19Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.
20Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.
21Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀.
22Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó.
23Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye.
24Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀.
25Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
26Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.
27Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni.
28On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia.
29Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn.
30Awọn ti o duro pẹ nibi ọti-waini; awọn ti nlọ idan ọti-waini àdalu wò.
31Iwọ máṣe wò ọti-waini pe o pọn, nigbati o ba fi àwọ rẹ̀ han ninu ago, ti a ngbe e mì, ti o ndùn.
32Nikẹhin on a buniṣán bi ejò, a si bunijẹ bi paramọlẹ.
33Oju rẹ yio wò awọn ajeji obinrin, aiya rẹ yio si sọ̀rọ ayidayida.
34Nitõtọ, iwọ o dabi ẹniti o dubulẹ li arin okun, tabi ẹniti o dubulẹ lòke òpó-ọkọ̀.
35Iwọ o si wipe, nwọn lù mi; kò dùn mi; nwọn lù mi, emi kò si mọ̀: nigbawo li emi o ji? emi o tun ma wá a kiri.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.