Owe 8
8
Yíyin Ọgbọ́n
1ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi?
2O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni.
3O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun.
4Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia.
5Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye.
6Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ.
7Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi.
8Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn.
9Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri.
10Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ.
11Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.
12Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu.
13Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira.
14Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara.
15Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ.
16Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye.
17Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi.
18Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo.
19Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ.
20Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ:
21Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn.
22Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ.
23A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà.
24Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ.
25Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi:
26Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye.
27Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun.
28Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu:
29Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye.
30Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀;
31Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia.
32Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi:
33Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ.
34Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi.
35Nitoripe ẹniti o ri mi, o ri ìye, yio si ri ojurere Oluwa.
36Ṣugbọn ẹniti o ṣẹ̀ mi, o ṣe ọkàn ara rẹ̀ nikà: gbogbo awọn ti o korira mi, nwọn fẹ ikú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Owe 8: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.