O. Daf 115
115
Ọlọrun Òdodo
1KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ.
2Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi?
3Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u.
4Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia.
5Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran.
6Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun.
7Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade.
8Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
9Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
10Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
11Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
12Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni.
13Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba.
14Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin.
15Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye.
16Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia.
17Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ.
18Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 115: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.