O. Daf 135

135
Orin Ìyìn
1Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa.
2Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa.
3Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn.
4Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀.
5Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ.
6Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo.
7O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá.
8Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko.
9Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo.
10Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba.
11Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani:
12O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀.
13Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran.
14Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀,
15Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia.
16Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran.
17Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn.
18Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
19Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa.
20Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa.
21Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 135: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀