O. Daf 14
14
Èrè Òmùgọ̀
1AṢIWERE wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun kò si. Nwọn bajẹ, nwọn si nṣe iṣẹ irira, kò si ẹniti nṣe rere.
2Oluwa bojuwò lati ọrun wá sara awọn ọmọ enia, lati wò bi ẹnikan wà ti oye ye, ti o si nwá Ọlọrun.
3Gbogbo wọn li o si jumọ yà si apakan, nwọn si di elẽri patapata; kò si ẹniti nṣe rere, kò si ẹnikan.
4Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ kò ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun, nwọn kò si kepè Oluwa.
5Nibẹ ni ẹ̀ru bà wọn gidigidi: nitoriti Ọlọrun mbẹ ninu iran olododo.
6Ẹnyin dojutì ìmọ awọn talaka, ṣugbọn Oluwa li àbo rẹ̀.
7Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá! nigbati Oluwa ba mu ikólọ awọn enia rẹ̀ pada bọ̀, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 14: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.