O. Daf 30
30
Adura Ọpẹ́
Orin Dafidi fun iya-si-mimọ́.
1EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.
2Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da.
3Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho.
4Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.
5Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ.
6Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai.
7Oluwa, nipa oju-rere rẹ, iwọ ti mu òke mi duro ṣinṣin: nigbati iwọ pa oju rẹ mọ́, ẹnu yọ mi.
8Emi kigbe pè ọ, Oluwa; ati si Oluwa li emi mbẹ̀bẹ gidigidi.
9Ere kili o wà li ẹ̀jẹ mi, nigbati mo ba lọ sinu ihò? erupẹ ni yio ma yìn ọ bi? on ni yio ma sọ̀rọ otitọ rẹ bi?
10Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi.
11Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure.
12Nitori idi eyi ni ki ogo mi ki o le ma kọrin si ọ, ki o má si ṣe dakẹ. Oluwa Ọlọrun mi, emi o ma fi iyìn fun ọ lailai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 30: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.