Sef 1
1
1Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hisikiah, li ọjọ Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda.
Ọjọ́ Ìdájọ́ Ọlọrun
2Oluwa wipe, emi o mu gbogbo nkan kuro lori ilẹ na patapata.
3Emi o mu enia ati ẹranko kuro; emi o mu ẹiyẹ oju ọrun kuro, ati ẹja inu okun, ati ohun idigbòlu pẹlu awọn enia buburu; emi o si ké enia kuro lori ilẹ, ni Oluwa wi.
4Emi o nà ọwọ́ mi pẹlu sori Juda, ati sori gbogbo ara Jerusalemu; emi o si ké iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa;
5Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori orule: awọn ti nsìn, ti nfi Oluwa bura, ti si nfi Malkomu bura;
6Ati awọn ẹniti o yipadà kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ẹniti kò ti wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère rẹ̀.
7Pa ẹnu rẹ mọ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitori Oluwa ti pesè ẹbọ kan silẹ̀, o si ti yà awọn alapèjẹ rẹ̀ si mimọ́.
8Yio si ṣe li ọjọ ẹbọ Oluwa, ti emi o bẹ̀ awọn olori wò, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo iru awọn ti o wọ̀ ajèji aṣọ.
9Li ọjọ na gan li emi o bẹ̀ gbogbo awọn ti nfò le iloro wò pẹlu, ti nfi ìwà-ipá on ẹ̀tan kún ile oluwa wọn.
10Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ohùn ẹkún yio ti ihà bodè-ẹja wá, ati hihu lati ihà keji wá, ati iro nla lati oke-kékèké wọnni wá.
11Hu, ẹnyin ara Maktẹsi, nitoripe gbogbo enia oniṣòwo li a ti ke lu ilẹ; gbogbo awọn ẹniti o nrù fàdakà li a ke kuro.
12Yio si ṣe li akokò na, li emi o fi fitilà wá Jerusalemu kiri, emi o si bẹ̀ awọn enia ti o silẹ sinu gẹ̀dẹgẹdẹ̀ wọn wò: awọn ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹ̃ni kì yio ṣe buburu.
13Nitorina ogun wọn o di ikógun, ati ilẹ wọn yio di ahoro: nwọn o kọ́ ile pẹlu, ṣugbọn nwọn kì yio gbe inu wọn, nwọn o si gbìn ọgbà àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini inu rẹ̀.
14Ọjọ nla Oluwa kù si dẹ̀dẹ, o kù si dẹ̀dẹ̀, o si nyara kánkan, ani ohùn ọjọ Oluwa: alagbara ọkunrin yio sọkun kikorò nibẹ̀.
15Ọjọ na ọjọ ibinu ni, ọjọ iyọnu, ati ipọnju, ọjọ ofò ati idahoro, ọjọ okùnkun ọti okùdu, ọjọ kũku ati okunkun biribiri,
16Ọjọ ipè ati idagirì si ilu olodi wọnni ati si iṣọ giga wọnni.
17Emi o si mu ipọnju wá bá enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitori nwọn ti dẹṣẹ si Oluwa: ẹjẹ̀ wọn li a o si tú jade bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ.
18Fàdakà wọn tabi wurà wọn kì yio lè gbà wọn li ọjọ ìbinu Oluwa: ṣugbọn gbogbo ilẹ̀ na li a o fi iná ijowu rẹ̀ parun: nitori on o fi iyara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na kuro.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sef 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.