Sef 2
2
Ìpè sí Ìrònúpìwàdà
1Ẹ kó ara nyin jọ pọ̀, ani, ẹ kójọ pọ̀ orilẹ-ède ti kò nani;
2Ki a to pa aṣẹ na, ki ọjọ na to kọja bi iyàngbò, ki gbigboná ibinu Oluwa to de ba nyin, ki ọjọ ibinu Oluwa ki o to de ba nyin.
3Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tutù aiye, ti nṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa-pẹ̀lẹ: boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu Oluwa.
Ìparun tí Yóo Dé Bá Àwọn Ìlú tí Wọ́n Yí Israẹli Ká
4Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, Aṣkeloni yio si dahoro: nwọn o le Aṣdodu jade li ọsangangan, a o si fà Ekronu tu kuro.
5Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ.
6Agbègbe okun yio si jẹ ibujoko ati agọ fun awọn olùṣọ agùtan, ati agbo fun agbo-ẹran.
7Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro.
8Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn.
9Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
10Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.
11Oluwa yio jẹ ibẹ̀ru fun wọn: nitori on o mu ki gbogbo òriṣa ilẹ aiye ki o rù; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi.
12Ẹnyin ara Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin.
13On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ihà ariwa, yio si pa Assiria run; yio si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginjù.
14Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ.
15Eyi ni ilu alayọ̀ na ti o ti joko lainani ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹnikan ti mbẹ lẹhìn mi: on ha ti ṣe di ahoro bayi, ibùgbe fun ẹranko lati dubulẹ si! olukuluku ẹniti o ba kọja lọdọ rẹ̀ yio pòṣe yio si mì ọwọ́ rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sef 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.