Sef 3
3
Ẹ̀ṣẹ̀ Jerusalẹmu ati Ìràpadà Rẹ̀
1EGBE ni fun ọlọ̀tẹ ati alaimọ́, fun ilu aninilara nì.
2On kò fetisi ohùn na; on kò gba ẹkọ́; on kò gbẹkẹ̀le Oluwa; on kò sunmọ ọdọ Ọlọrun rẹ̀.
3Awọn olori rẹ̀ ti o wà lãrin rẹ̀ kiniun ti nke ramùramù ni nwọn; awọn onidajọ rẹ̀ ikõkò aṣãlẹ ni nwọn; nwọn kò sán egungun titi di owurọ̀.
4Awọn woli rẹ̀ gberaga, nwọn si jẹ ẹlẹtàn enia: awọn alufa rẹ̀ ti ba ibi mimọ́ jẹ: nwọn ti rú ofin.
5Oluwa li olõtọ lãrin rẹ̀, kì yio ṣe buburu: li orowurọ̀ li o nmu idajọ rẹ̀ wá si imọlẹ, kì itase; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itìju.
6Mo ti ke awọn orilẹ-ède kuro; ile giga wọn dahoro; mo sọ ita wọnni di ofo, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja ihà ibẹ̀: a pa ilu wọnni run, tobẹ̃ ti kò si enia kan, ti kò si ẹniti ngbe ibẹ̀.
7Emi wipe, Lõtọ iwọ o bẹ̀ru mi, iwọ o gba ẹkọ́; bẹ̃ni a kì ba ti ke ibujoko wọn kuro, bi o ti wù ki mo jẹ wọn ni iyà to: ṣugbọn nwọn dide ni kùtukùtu, nwọn ba gbogbo iṣẹ wọn jẹ.
8Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run.
9Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i.
10Lati oke odò Etiopia awọn ẹlẹbẹ̀ mi, ani ọmọbinrin afunká mi, yio mu ọrẹ mi wá.
11Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi.
12Emi o fi awọn otòṣi ati talakà enia silẹ pẹlu lãrin rẹ, nwọn o si gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa.
13Awọn iyokù Israeli kì yio hùwa ibi, bẹ̃ni nwọn kì yio sọ̀rọ eke, bẹ̃ni a kì yio ri ahọn arekerekè li ẹnu wọn: ṣugbọn nwọn o jẹun nwọn o si dubulẹ, ẹnikan kì yio si dẹ̀ruba wọn.
Orin Ayọ̀
14Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu.
15Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ.
16Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀.
17Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ.
18Emi o kó awọn ti o banujẹ fun ajọ mimọ́ jọ awọn ti o jẹ tirẹ, fun awọn ti ẹgàn rẹ̀ jasi ẹrù.
19Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn.
20Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sef 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.