1 Johanu 5

5
Ìgbàgbọ́ nínú ọmọ Ọlọ́run
1 Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. 2Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 3 Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira, 4 nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. 5Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
6 Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí. 7Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí. 8Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan. 9 Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀. 10 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀. 11Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. 12 Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
Àwọn àfiyèsí ìparí
13 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. 14 Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; 15Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú: èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí. 17Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀: ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án. 19Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà. 20 Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.
21Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Johanu 5: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀