2 Johanu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Lẹ́tà kékeré yìí ni Johanu kọ sí obìnrin Kristiani kan tí Johanu mọ̀, láti mú kí ìfẹ́ tòótọ́ gbilẹ̀ láàrín àwọn Kristiani àti láti kìlọ̀ nípa àwọn atannijẹ tí wọn ń bọ́ wá sínú ayé. Johanu rọ̀ wọ́n láti má ṣe lọ́wọ́ nínú aburú, ṣùgbọ́n láti dúró lórí òtítọ́.
Ẹ̀kọ́ inú lẹ́tà yìí ni pé, ó yẹ kí Kristiani ṣọ́ra kí wọn sì kíyèsára lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ èké, wọ́n gbọdọ̀ mọ̀ pé ẹ̀kọ́ èké ń bẹ, wọ́n sì gbọdọ̀ múra láti mú un kúrò tó bá wáyé. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọdọ̀ gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìfáàrà 1-3.
ii. Ìgbé ayé ìfẹ́ 4-6.
iii. Kíkọ ìlòdì sí Kristi àti ẹ̀tàn sílẹ̀ 7-13.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

2 Johanu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀