Gẹnẹsisi 18:9-15

Gẹnẹsisi 18:9-15 YCB

Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ńkọ́?” Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.” Nígbà náà ni OLúWA wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó: Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?” Nígbà náà ni OLúWA wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún OLúWA? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.” Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín. Ṣùgbọ́n OLúWA wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.”