Jobu 26

26
Ìdáhùn Jobu
1Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé:
2Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
3Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
4Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?
5“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
6Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
ibi ìparun kò sí ní ibojì.
7Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
8Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
9Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10Ó fi ìdè yí omi Òkun ká,
títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
12Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
13Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
14Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jobu 26: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀