Jobu 27

27
1Pẹ̀lúpẹ̀lú Jobu sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé:
2“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ,
àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́;
3(Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi,
àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.)
4Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké,
Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
5Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre;
títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.
6Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́;
àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.
7“Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú,
àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo.
8Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè,
nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?
9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀,
nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i?
10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè?
Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo?
11“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run:
ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.
12Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i;
kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín?
13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè:
14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;
àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.
15Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:
àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.
16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,
tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
17àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;
àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,
àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.
19Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́;
Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ
20Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn;
ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.
21Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ;
àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.
22Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí;
òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
23Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí,
wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jobu 27: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀