Òwe 20

20
1Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọtí líle
ẹnikẹ́ni tí ó bá fi tànjẹ kò gbọ́n.
2Ìbẹ̀rù ọba dàbí kíké e kìnnìún;
ẹnikẹ́ni tí ó bá mú un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
3Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà,
ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
4Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ,
nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
5Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn;
ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
6Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń sọ pe àwọn ní ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn,
ṣùgbọ́n kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòtítọ́.
7Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù
ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́
yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9Ta ni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,
mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ
Olúwa kórìíra méjèèjì.
11Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀
nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
12Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran
Olúwa ni ó dá méjèèjì.
13Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà.
Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
14“Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí
nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán,
yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí.
15Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ
ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
16Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò;
mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
17Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn
ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀.
18Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn
bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà.
19Olófòófó a máa tú àṣírí
nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀.
20Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,
ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
21Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀
kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
22Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ”
Dúró de Olúwa yóò sì gbà ọ́ là.
23 Olúwa kórìíra òdínwọ̀n èké.
Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24 Olúwa ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn
Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá
nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
26Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká;
Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
27Àtùpà Olúwa ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn
a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
28Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́,
nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
29Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn,
ewú orí ni iyì arúgbó.
30Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ,
pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Òwe 20: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀