Saamu 23:1-6

Saamu 23:1-6 YCB

OLúWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́; Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn Láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ wọ́n ń tù mí nínú. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi; ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé OLúWA títí láéláé.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Saamu 23:1-6

Saamu 23:1-6 - OLúWA ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé OLúWA
títí láéláé.