Orin Solomoni 3
3
1Ní orí ibùsùn mi ní òru
mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;
mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
2Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,
ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;
Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.
3Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi
bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”
4Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀
ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ
títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,
sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi
5Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
6Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá
bí ọ̀wọ̀n èéfín
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára
pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?
7Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,
àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,
àwọn akọni Israẹli,
8Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,
gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,
idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,
wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru
9Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;
o fi igi Lebanoni ṣe é.
10Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀
o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀
Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,
inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí
“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”
11Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,
kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,
adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e
ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,
ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Orin Solomoni 3: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.