Sefaniah 1
1
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.
Ìkìlọ̀ fún ìparun tí ń bọ̀
2“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò
lórí ilẹ̀ náà pátápátá,”
ni Olúwa wí.
3“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko
kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú
ọ̀run kúrò àti ẹja inú Òkun, àti
ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn
ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”
ni Olúwa wí.
Ìlòdì sí Juda
4“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda
àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.
Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà
pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
5àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,
àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,
àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,
tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.
6Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa;
Àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.”
7 Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Olódùmarè,
nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.
Olúwa ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀,
ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.
8“Ní ọjọ́ ẹbọ Olúwa,
Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn
ọmọ ọba ọkùnrin,
pẹ̀lú gbogbo
àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
9Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ
gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu-ọ̀nà,
tí wọ́n sì kún tẹmpili àwọn ọlọ́run wọn
pẹ̀lú ìwà ipá àti ẹ̀tàn.
10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí,
“Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja,
híhu láti ìhà kejì wá àti
ariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
11Ẹ hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní (Maktẹsi) agbègbè ọjà,
gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò,
gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.
12Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jerusalẹmu kiri pẹ̀lú fìtílà,
èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn,
tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn,
àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘Olúwa kì yóò ṣe nǹkan kan
tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
13Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógun,
àti ilé wọn yóò sì run.
Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n
wọn kì yóò gbé nínú ilé náà,
wọn yóò gbin ọgbà àjàrà,
ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí
wáìnì láti inú rẹ̀.”
Ọjọ́ ńlá Olúwa
14“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀
kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún
àwọn alágbára ní ọjọ́ Olúwa yóò korò púpọ̀,
15Ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú,
ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú,
ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro
ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba,
ọjọ́ kurukuru àti òkùnkùn biribiri,
16ọjọ́ ìpè àti ìpè ogun
sí àwọn ìlú olódi
àti sí àwọn ilé ìṣọ́ gíga.
17“Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí
ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú,
nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa.
Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku
àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
18Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn
kì yóò sì le gbà wọ́n là
ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.”
Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná
ìjowú rẹ̀ parun,
nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí
gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ayé.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Sefaniah 1: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.