I. Joh 5:11-13
I. Joh 5:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ̀rí na si li eyi pe Ọlọrun fun wa ni ìye ainipẹkun, ìye yi si mbẹ ninu Ọmọ rẹ̀. Ẹniti o ba ni Ọmọ, o ni ìye; ẹniti kò ba si ni Ọmọ Ọlọrun, kò ni ìye. Nkan wọnyi ni mo kọwe rẹ̀ si nyin ani si ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe ẹnyin ni iye ainipẹkun, ani fun ẹnyin ti o gbà orukọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́.
Pín
Kà I. Joh 5I. Joh 5:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè. Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́.
Pín
Kà I. Joh 5