I. Sam 28:7-8
I. Sam 28:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ. Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi.
I. Sam 28:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.” Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.” Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”
I. Sam 28:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.” Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”