Mal 3:11-12
Mal 3:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Pín
Kà Mal 3Mal 3:11-12 Yoruba Bible (YCE)
N kò ní jẹ́ kí kòkòrò ajẹnirun jẹ ohun ọ̀gbìn yín lóko, ọgbà àjàrà yín yóo sì so jìnwìnnì. Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa pè yín ní ẹni ibukun, ilẹ̀ yín yóo sì jẹ́ ilẹ̀ ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”
Pín
Kà Mal 3Mal 3:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò sì bá kòkòrò ajẹnirun wí nítorí yín, òun kò sì ni run èso ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni àjàrà inú oko yín kò ní rẹ̀ dànù,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nígbà náà ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì pè yín ni alábùkún fún, nítorí tiyín yóò jẹ́ ilẹ̀ tí ó wu ni,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.
Pín
Kà Mal 3