Mọ Ohùn Ọlọ́run // Kọ́ L'áti Pàdé Rẹ̀Àpẹrẹ

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ọjọ́ 2 nínú 4

Bí Afẹ́fẹ́ Ṣe ń Fẹ́ (Tí ó Sì ń Mú Àlàáfíà Wá)

Ẹ̀mí Mímọ́ nínú wa, eléyì ní a gbọ́ fún-un yín:

L'áti ọjọ́ pípẹ́ ni o ti gbọ́ ohùn mi. O ti dá mi mọ̀ kí o tó mọ̀ wí pé èmi ni. Ohùn ìtùnú ni ó jẹ́ ní ìgbà tí ẹ̀rù ń bà ọ́, ohùn ìmúlọ́kànle ní ìgbà tí ìdààmú dé bá ọ. Òróró ìtura ni ó jẹ́ fún ọgbẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí kìí ṣe ọ̀rọ̀ gidi — ohùn ìwàláàyè, ohùn tí ó ti di bárakú fún ọ. Báwo ni ìwọ kò ṣe lè ṣe àkíyèsí afẹ́fẹ́ tí ó ń fẹ́ lẹlẹ lé ojú rẹ? Báwo ni ìwọ kò ṣe ní ìmọ̀lára ìfẹ́ tí ó ń mí sí ọ l'ára?

Mo jẹ́ ohùn fún àwọn tí ó dá kẹ́, àti ohùn fún àwọn tí ó ń kọ orin. Mo jẹ́ ohùn fún ìdákẹ́jẹ́, àti ohùn fún ìjì líle. Mo gbé àwọn tí ó ti rẹ̀ s'ókè, mo sì mú àwọn tí ó ń tẹ̀ s'íwájú ró, tí wón ń rìn, tí wón ń wo ojú mi. Nwọ́n ṣí ọwọ́ wọn sí òkè bí wọ́n ṣe ń rìn lọ. Nwọ́n lè gun òkè, wọ́n sì lè dúró ṣinṣin.

Ní ìtorí wí pé ayé yí kò lè mú ìparun bá ọkàn rẹ. Rárá, ìyẹn kò ṣeéṣe. Àwọn nǹkan tí ó ń fa ìrora, ẹkún, ìpọ́njú, ni àkókò tí òkùnkùn bá mú ìbànújẹ́ dání, tí àlàáfíà sì jìnà réré. Ọmọ mi mú àlàáfíà wá. Afẹ́fẹ́ bo ilẹ̀ káàkiri. Ní ìtorí wí pé l'áti wà ní àlàáfíà ju ìmúlọ́kànle, ìgboyà, àti iṣẹ́ àṣekára lọ. Afẹ́fẹ́ náà—tí o ní ìmọ̀lára rẹ̀ tí o sì ń tẹ́lè, ní àwọn èròjà àlàáfíà nínú. Ọmọkùnrin, ọmọbìrin, o mọ̀ mí dájúdájú. Ó lè mú àlàáfíà — bá ara rẹ, bá àwọn ẹlòmíràn, àti bá ayé rẹ — ní'torí wí pé ó mọ rírì ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí kò f'ara sin ju nǹkan tí a lè fi ojú rí lọ.

O ti ní ìmọ̀lára afẹ́fẹ́. O sì ti ní ìmọ̀lára ẹ̀mí mi tí ó ń mi nínú rẹ. O ti tẹ́ etí s'ílẹ̀ fún-un, torí o mọ̀ ọ́ ní olùrànlọ́wọ́, atọ́nà rẹ nínú ohun gbogbo. Mo fẹ́ ràn ọ́ l'ọ́wọ́ l'áti dá mi mọ̀ síi nísinsìnyí. Mo fẹ́ ṣe àfikún ìfẹ́ rẹ l'áti sún mọ́ mí dáadáa. Ṣùgbọ́n mo fi eléyìí lé ọ l'ọ́wọ́. Mo fi s'ílẹ̀ fún ọ kí ó jíròrò bí o bá fẹ́ kí ìfẹ́ rẹ fún mi jinlẹ̀ sìí. Ní'torí afẹ́fẹ́ a máà pa'pò dà, ṣùgbọ́n kò fi ọ́ s'ílẹ̀ ní ìgbà kan. Afẹ́fẹ́ náà fà ọ́ sí òkè, ó sì gbé ọ, tí o bá gbà á láàyè.

Ní'torí náà iṣẹ́ wà fún ọ l'áti ṣe. O ní ànfààní l'áti yàn l'áti tẹ̀ sí'wájú, nípa jíjinlẹ̀ síi dé ibi tí mo ti lè fi bí mo ṣe jẹ́ hàn ọ́ síi. Àwa méjèèjì l'ápapọ̀, ṣé o ri bẹ́ẹ̀ yẹn? O wà ní ibí nísinsìnyí, pẹ̀lú mi, ẹ̀mí rẹ sì wà láàyè nínú ẹ̀mí mi tí ó ń gbé inú rẹ. Ò ń d'àgbà, o sì ń pọ̀ si nínú ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìdúró ṣinṣin nínú mi. O yàn l'áti gbọ́ mi. O yàn l'áti wá mi rí. Ìjọ̀wọ́ ara rẹ pẹ̀lú inú àti ọkàn kan l'áti máa rìn, bẹ́ẹ̀ ni rìnrìn ni mo sọ. O gun òkè l'àti rìn àti jọ̀wọ́ ara rẹ kí o sì ní ìmọ̀lára afẹ́fẹ́ ní ojú rẹ, afẹ́fẹ́ náà sì sọ̀rọ̀ sí ọkàn rẹ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ̀.

O mọ̀ mí. O mọ̀ mí. Mo fẹ́ kí o mọ̀ mí síi.

Iṣẹ́ ṣíṣe:

À ń wá àlàáfíà ní tipátipá bí ó ti wù kí ó kéré mọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?  

Ó dà bíi wí pé àlàáfíà s'ọ̀wọ́n ní àwọn àkókò yí, ní ìgbé ayé wa bí ayé ṣe ń yí lọ yìí.

Ṣùgbọ́n ńkankan wà ní'pa àlàáfíà . . . a kò lè wá aàlàfíà kí a sì ríi fún'ra wa. A kò lè ṣiṣẹ́ l'áti rí àlàáfíà gba fún'ra wa. Kìí ṣe àlàáfíà tí a nílò nìyẹn. Kìí ṣe èyí tí ó kún ojú òṣùwọ̀n . . . nínú ọkàn wa. Kìí ṣ'iṣẹ́ bayìí, ohun yòówù kí a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìran-ara-eni-lọ́wọ́.

Ní'torí náà, ẹ jẹ́ kí a gbé àṣà sì ẹ̀gbẹ́ kan kí a sì ṣe àyẹ̀wò ọ̀nà míràn.

Ẹ jẹ́ ki . . . dípò tí a fí ń wá àlàáfíà tikalarẹ . . . a wá ojú réré Ọlọ́run jú lọ. Ẹ jẹ́ kí a kọ́ bí a ṣe lè mọ si ní'pa Ọlọ́run, kí àlàáfíà Rẹ̀ lè jẹ́ àlàáfíà wa . . . nínú àìrójú-ráyè wa.

Ẹ jẹ́ ki a ní àfojúsùn lé bí a ṣe lè mọ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣé ń ṣ'iṣẹ́ ní ipasẹ̀ wa loni, èémí Ọlọ́run nínú wa.

Ní'torí náà, a ní ànfààní l'áti yàn. Ìwọ náà ní ànfààní l'áti yàn.

Rìn sí'wájú. Tàbí kí o dúró ní ibi tí o wà. Lọ jinlẹ̀ síi. Tàbí kí o dúró ní ibi tí kò ti sí ewu.

Tàbí kí ó yàn l'áti tiraka l'áti t sí'wájú gẹ́gẹ́ bíi olùṣàkóso.

Ní àkókò kọ̀ọ̀kan, o lè yàn . . . l'áti dúró tìí, tí ara rẹ, tàbi kí o má ṣe ńkankan

Dúró jẹ́ẹ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀, kí ó sì yí ọkàn àti inú rẹ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bí ó ṣe ń bá ọ sọ̀rọ̀ nísinsìnyí lè má jẹ́ ohun tí ó ń retí lọ́dọ̀ rẹ . . . Lẹhin ohun gbogbo, Ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàlẹ́nu, ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ sì ni eléyì, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà. . .

"Afẹ́fẹ́ náà fà ọ́ sí òkè, ó sì gbé ọ, tí o bá gbà á láàyè."

Jésù, à ń retí Rẹ . . .

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ohùn Ọlọ́run lè wá bíi ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tàbí ìró ìjì líle. Ohun gbòógì ni l'áti dá a mọ̀, bí ó ti wù kí ó wá—àti kí a gbàgbọ́ wí pé Ó dára, wí pé Ó tóbi ju èyíkéyìí àwọn ìjàkadì wa lọ. Bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí kí o sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síí kọ́ bí a ṣe lè pàdé Rẹ̀, ohùn Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀ —kí o sì da ara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ń ní ìrírí Rush |Ẹ̀mí Mímọ́ Ní Ayé Òde-Òní.

More

A dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Gather (Loop/Wire) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: https://rushpodcast.com