Mọ Ohùn Ọlọ́run // Kọ́ L'áti Pàdé Rẹ̀Àpẹrẹ

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ọjọ́ 3 nínú 4

Òye-inú àti Àròjinlẹ̀

Ẹ̀mí-mímọ́ inú wa, ohun tí a gbọ́ nípa rẹ nìyìí:

Ọ̀nà tí mo tọ̀ dé ọ̀dọ̀ rẹ lè má lọ́ jáí. Ó lè má jẹ́ ní jẹ̀lẹ̀ńkẹ́—àti pàápàá jùlọ ní ọ̀nà tí o ní ní èrò. Nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa mi ni mo fẹ́ẹ́ fi hàn ọ́, o kò rí ńńkan bí?. Ibi kan wà tí ó jinlẹ̀ tí mo fẹ́ mú ọ lọ. Àwọn ǹǹkan wà tí mo fẹ́ fi hàn ọ́—kì í sì í ṣe ojú rẹ ni yíó rí àwọn ohun tí mo fẹ́ kí o rí. Nítorí báyìí ni màá ṣe lo òye-inú rẹ bí o bá gbà mí láàyè.

Ní àkọ́kọ́, rántí pé kì í ṣe nínú ìmọ́lẹ̀ ní mo ti kọ́ dá ọ. Nítorínáà fi òye-inú wo òkùnkùn. Lẹ́hìnnáà wo òye ìmọ́lẹ̀ . . . O ti wà kí n tó dá ọ ní inú ara. Ohun tí mo sì fẹ́ẹ́ fi hàn ọ́ wà, kódà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí—àti ní gbogbo ìgbà—bíótilẹ̀jẹ́pé kò ì tí ì fi ara hàn nínú ara ní ayé yìí. Ohun ti ara tí o fi ojú rí hàn sí ọ nípa ìrírí tí o ní nínú ẹ̀mí rẹ, nínú ọkàn rẹ. O leè rí, gbọ́ òórùn, fí ọwọ́ bà àti ní ìrírí nínú ẹ̀mí rẹ, ohun tí mo fi fún ọ láti ní ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú mi. Àwọn ohun tí o bá sì rí, tí o ní ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú mi, yíó fi irú ohun tí mo jẹ hàn o sí i.

Bẹ́ẹ̀ni, o lè kà nípa mi. Bẹ́ẹ̀ni, o lè gbọ́ ohùn mi nínú ọkàn rẹ. Bẹ́ẹ̀ni, o lè gba àdúrà kí o sì tẹ̀lé àti kí o dáhùn sí ọgbọ̀n tí mo fi fún ọ, ṣùgbọ́n ṣé o fẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ṣe o fẹ́ẹ́ rí ohun tí oò ní ní èrò rí? Ṣé o fẹ́ kí n tú ara mì jáde sí inú ọkàn rẹ kí o ba à lè ní ìrírí ohun tí oò ní ní èrò rí? Ṣe o fẹ́ kí n ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wo òye-inú?

Di ojú rẹ, ẹni mi ọ̀wọ́n. Jẹ́ kí n mú ọ parọ́rọ́. Ó ti yá báyìí . . . lọ jinlẹ̀ báyìí. Jẹ́ kí n mú ọ jinlẹ̀. Ní báyìí, ọwọ́ mì rè é. Ṣé o rí í? Mo ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára rẹ̀. Wòó báyìí, kì í ṣe pẹ̀lú ojú rẹ. Wòó pẹ̀lú ọkàn rẹ. Rí i pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ. Ohun tí ó mú ọgbọ́n wá kò ní láti mú ọgbọ́n wá mọ́. Àpẹẹrẹ tuntun ni mí. Jẹ́ kí n tú jáde, ní gbangba wálíà, ohun tí o gbàgbọ́ nípa mi, ẹni tí ó ní ní èrò pé mo jẹ́.

Ṣé ọ gbàgbọ́ pé mo dára? Jẹ́ kí n fi hàn ọ́ bí ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣé o gbàgbọ́ pé mo ní agbára? Jẹ́ kí n fi díẹ̀ hàn ọ́ nínú ohun tí mo lè ṣe. Ṣé o gbàgbọ́ pé mo wà pẹ̀lú rẹ, pé mò ń mú ìwòsàn wá, pé mo mú àwọn íràwọ̀ àti òṣùpa àti ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ́ ìṣẹ̀dá-ayé tí o kò leè kà tán--pé mo mú wọn ní ọwọ́ mi? Mo fẹ́ mú ọ rin ìrìn-àjò, ìwọ àti èmi nìkàn. Ṣùgbọ́n o ní láti fi ọkàn tán mi—kí o sì kó gbogbo ìkọnimú àti iyèméji tì sí ẹ̀gbẹ́ kan ná. Di ojú rẹ . . O sì le là wọ́n s'ílẹ̀ . . . Mo lè ṣe iṣé pẹ̀lú ojú rẹ ní l'ílà s'ílẹ̀ kedere náà. . . Óyá jẹ́ kí á lọ.

Ìdánrawò:

Ìwọ, ọ̀rẹ́ mi, ni a pè làti kálọ sí ìrìn-àjò, ní báyìí báyìí.

A ti bèèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ rẹ:

Ṣé ọ fẹ́ kí Ẹ̀mímímọ́ tú ara rẹ̀ jáde sí inú ọkàn rẹ tó bẹ́ẹ̀ ti wà á ní ìrírí tí o kò ní ní èrò rí? Ṣé o fẹ́ kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wo òye ohun tí ojú rẹ kò ì tí ì rí rí?

Làti ṣe èyí, o ní láti ṣetán láti sí ọkàn àti ẹ̀mí rẹ payá. O ní láti ṣetán láti rí, láti gbọ́ àti láti ní ìrírí ohun ti o kò ní rí . . . Ṣé o ṣetán láti jẹ́ kí Ẹ̀mímímọ́ sí ọkàn rẹ payá sí í . . . sí ìfẹ́ sí í, sí ìyanu sí í, sí ẹwà sí í, sí ayọ̀ sí i, sí àlááfíà sí í, àti ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀?

Ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan yanturu fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa . . . láti gbọ́, láti ní ìrírí, láti mọ̀, láti fẹ́. . . A sì ń rí àpẹẹrẹ rere, òye rẹ̀ . . . ògo rẹ̀, ẹwà rẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ ní ayé yìí. Ṣùgbọ́n ìrírí wa ní akùdé. Ọgbọ́n wa ní akùdé. Síbẹ̀ Ọlọ́run wa, nínú agbára àti ìfẹ́ àti iṣẹ́-àtinúdá rẹ̀, kò ní akùdé. Òun sì rè é, Ó ń bèèrè lọ́wọ́ wa, ní báyìí, bí a bá ṣetán láti jọ̀ọ̀wọ́ ìwòye-inú wa fún Un . . . bí àwa, ní báyìí, bá fẹ́ láti ní ìrírí ohun tí Ó jẹ́ sí í ní ayé wa, bẹ̀rẹ̀ láti òní lọ, ní àkókò yìí gan an!

Ẹ̀mímímọ́, jẹ́ ojú wa báyìí. Jẹ́ etí wa. Jẹ́ imú ìgbóòórùn wa, jẹ́ ahọ́n ìtọ́wò wa, ọwọ́ ìfibà wa. A fẹ́ ọ sí i. A fẹ́ kí O yí àwọn ìgbàgbọ́ òdì tí a ní nípa rẹ po, kí O yí ìmọ̀ tí ó lòdì nípa ẹni tí O jẹ́ àti ohun tí O lè ṣe. A sì fẹ́ kí O mú ọkàn, ẹ̀mí, ojú-ìwòye wa gbòòrò tóbẹ́ẹ̀ tí a ó rí Ọ, mọ̀ Ọ́, ní ìrírí Rẹ pẹ̀lú ojú-ẹ̀mí wa tí ó lè ṣe ohun tó pọ̀ sí í, tó pọ̀ rékọjá, pẹ̀lú Rẹ, ju kí ó rí ìran lásán lọ.

Baba, mú wa jinlẹ̀ sí inú ìyanu àti ọláńla àti ẹwà. Jẹ́ kí á ní ìrírí ìfẹ́tó ga jùlọ. Ní àkókò yìí a dúró, ní ìrètí àti ìfojúsọ́nà, dè Ọ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Recognizing God's Voice // Learn to Encounter Him

Ohùn Ọlọ́run lè wá bíi ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tàbí ìró ìjì líle. Ohun gbòógì ni l'áti dá a mọ̀, bí ó ti wù kí ó wá—àti kí a gbàgbọ́ wí pé Ó dára, wí pé Ó tóbi ju èyíkéyìí àwọn ìjàkadì wa lọ. Bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí kí o sì bẹ̀ẹ̀rẹ̀ síí kọ́ bí a ṣe lè pàdé Rẹ̀, ohùn Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀ —kí o sì da ara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin tí ń ní ìrírí Rush |Ẹ̀mí Mímọ́ Ní Ayé Òde-Òní.

More

A dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Gather (Loop/Wire) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: https://rushpodcast.com