Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ
“ÌSỌNIJÍ – Ṣíṣe Ìparẹ́ Ìyàn”
Ní ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn mo kà nípa iṣẹ́-ìwádìí kan tí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ọpọlọ Jonathan Haidt ṣe. Ọkùnrin yìí ṣe àgbékalẹ̀ eré ìdárayá àfọkànta kan, tó lọ báyìí:
Wọ́n fún àwọn olùkópa ní ìtàn kékeré kan nípa ìgbésí ayé ẹnìkan láti kà. Wọ́n wá rọ àwọn olùkópa yìí láti fi ojú inú rí ẹni tí wọ́n ka ìtàn rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọmọ wọn (l'óbìnrin). Ìtàn tí àwọn olùkópa kà yìí dá lé àyànmọ́ ọmọbìnrin náà, tí kò sì ṣeé yí padà. A kò tíì bíi ọmọbìnrin yìí, ṣùgbọ́n a óò bi láìpẹ́, ìtàn yí sì ni ibi tí ayé ọmọ náà ń doríkọ. Àwọn olùkópa wá ní àǹfààní láti ṣe àtúntò sí ìtàn yí láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún. Pẹ̀lú ẹfun ìpàwérẹ́, wọ́n lè pa ǹkan tí kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn rẹ́ kúrò nínú ìtàn ọmọbìnrin náà.
Àfojúsùn iṣẹ́ ìwádìí náà wá nìyí: Kíni ǹkan àkọ́kọ́ tí o máa parẹ́?
Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa súré ṣe ìparẹ́ àwọn ìpèníjà ẹ̀kọ́, ìjàmbá ọkọ̀, àti àwọn ìpèníjà àìlówó. A fẹ́ràn àwọn ọmọ wa, a ó sì ní fẹ́ kí wọ́n gbé ìgbésí ayé tó ní kùdìẹ̀-kudiẹ nínú. Gbogbo wa la máa fẹ́ ìgbé ayé tí kò ní ìrora tàbí ìpọ́njú nínú fún àwọn ọmọ wa.
Àmọ́, bèrè lọ́wọ́ ara rẹ: Ṣé ǹkan tó dára jù ni èyí?
Ǹjẹ́ a tilẹ̀ lérò wípé ìgbésí ayé tí kò ní ìjánu ni yóò mú inú àwọn ọmọ wa dùn bí? Tí o bá lọ pa ìpèníjà kan rẹ́ tí kò bá mú wọn jí ìjí-òdodo nípa àdúrà ńkọ́? Tí o bá lọ pá ìpèníjà kan rẹ́ tí kò bá fi ipasẹ̀ ìdùnnú àìnípẹ̀kun hàn wọ́n ńkọ́? Tí o bá lọ pa ìrora tàbí ìjìyà kan rẹ́ tí kò bá jẹ́ ohun tí yóò mú wọn sá tọ Ọlọ́run lọ ńkọ́? Tí o bá lọ pa ìdojúkọ kan rẹ tí kò bá mú wọn jí gìrì sí ètò Ọlọ́run fún ayé wọn ńkọ́?
Òtítọ́ tó korò ni, àmọ́ olùkópa àkọ́kọ́ sí ìdàgbàsókè wa nípa ti ẹ̀mí kìíṣe ìwàásù, ìwé tí à ń kà, tàbí ìpàdé ojúlé; olùkópa tó jù fún ìdàgbàsókè wa nípa ti ẹ̀mí ní onírúurú ìdojúkọ. Mo lè sọ èyí pẹ̀lú ìgboyà nítorí ìrírí mi, kíkà àwọn àkọsílẹ̀ ẹlòmíràn nípa ìdàgbàsókè ti ẹ̀mí, àti àwọn ẹ̀rí tí mo ti tùjọ níbi ìgbanimọ̀nràn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. AHA a máa ṣúyọ látinú ìjìyà, ìfàsẹ́yìn, àti onírúurú ìpèníjà inú ayé. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló lè tọ́ka sí irú àwọn àkókò yí gẹ́gẹ́bí ìgbà ìsọjí ẹ̀mí tó ga jù.
* Àkókò wo ní ìgbésí ayé rẹ ní ìrírí ìdàgbàsókè ẹ̀mí tó ga jù? Ṣé ìgbà ọ̀pọ̀ ni, àbí àkókò ọ̀nwọ́n-gógó? Àbí Ọlọ́run tilẹ̀ ń gbìyànjú láti mú ọ dàgbà si nípasẹ̀ àwọn ìdánwò àti ìdojúkọ tí kò rọrùn ni?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?
More