Ìyípadà Ọmọ Onínàkúnàá pẹ̀lú Kyle IdlemanÀpẹrẹ

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

Ọjọ́ 5 nínú 7

“ÌṢÒÓÓTỌ́ – Ìṣòóótọ́ tí ń Mú Ìwòsàn Wá”

Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ní òye tí wọ́n sì gba bí ìṣòóótọ́ ti ṣe pàtàkì tó, láàárín ara wọn àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Nínú Jòhánù Kínní, Bíbélì fi yéwa wípé nígbà tí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Ọlọ́run, Òhun jẹ́ olóòótọ́ àti oníìdájọ́ láti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn àti láti wẹ̀ wá kúrò nínú gbogbo àìmọ́. Bíbélì tún sọ nípa Jésù wípé ó gbé gbogbo ìjìyà tó tọ́ síwa sórí ara Rẹ̀ nígbà tó kú lórí igi àgbélébùú. Jésù kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí Ọlọ́run yóò dárí gbogbo wọn jìn nígbà tí mo bá jẹ́wọ́.

Lọ́pọ̀ ìgbà, a máà gba ara wa níyànjú wípé a kò ní láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: “Ní ìwọ̀ngbà tí mo bá ńṣe ìṣòóótọ́ pẹ̀lú ara mi àti Ọlọ́run, ìyẹn náà tó.” Àmọ́ AHA nílò ju èyí lọ.

Jákọ́bù 5:16 sọ nípa ìjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa àti gbígbàdúrà fún ẹnì kejì wa “kí o ba lè rí ìwòsàn.” Nígbà tí a bá ṣe ìṣòóótọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, Òhun yóò dárí jì wá, àmọ́ nígbà tí a bá sòótọ́ pẹ̀lú ọmọlàkejì wa, a máa ṣàwárí ìwòsàn.

Kíni “ìwòsàn” yí wá túmọ̀ sí?

Óda, ṣíṣe ìjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún ọmọlàkejì wa yóò mú wa jí gìrì àti wípé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàwarí ìkíni lẹ́yìn tí a nílò láti borí gbogbo làálàá wa. Nígbà tí a bá mú ǹkan tí a ti fi pamọ́ sínú òkùnkùn tí a sì wọ́ọ tuurutu bí ó ti ń jà pẹ̀lú ariwo wá sínú ìmọ́lẹ̀, a óò rí wípé yóò pàdánù èyí tójù nínú agbára rẹ̀ lóríi wa.

Àti wípé ìwòsàn tí Jákọ́bù sọ̀rọ̀ rẹ̀ ká geere ju bí o ti lérò lọ. Gbé èyí yẹ̀wọ̀: ìwé kan tí kò nííṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ọgbọ́n-orí tí a pe àkọlé rẹ ní "Fífi Arada Ìsaápọn" jẹ́rìí sí agbára ìwòsàn tó wà nínú ìjẹ́wọ́. Olùkọ̀wé náà sọ wípé, “àwọn ènìyàn tí máa sábà ní àṣírí a máa ní ìpèníjà nípa ti ara àti ọpọlọ, ju àwọn tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀… [ní àfikún] àníyàn tó ga, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, àti àwọn ìmọ́lára bíi ẹ̀yìn ríro àti orí fífọ́… Ìtura tí ń tẹ̀lé ìjẹ́wọ́ gbogbo àṣírí ibi nípa ara wa ni yóò bo gbogbo ìtìjú tó máa ń kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ mọ́lẹ̀.”

Òwe 28:13 tún sọ̀rọ̀ nípa àwárí yìí: “Ẹniti o bo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọlẹ kì yio ṣe rere: ṣugbọn ẹnikẹni ti o jẹwọ ti o si kọ̀ ọ silẹ yio ri ãnu.”

* Ọ̀nà wo ni ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún ẹlòmíràn ti ràn ọ́ lọ́wọ́ ní àtẹ̀yìnwá? Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ kan wà tí ìwọ ń bò mọ́lẹ̀, tí o kò sì ṣetán láti mú wọn wá sínú ìmọ́lẹ̀?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Prodigal Son Transformation With Kyle Idleman

A fa ètò yí jáde látinú ìwé Kyle Idleman "AHA," máa fọkàn báalọ bí ó ti ń ṣàwarí àwọn ǹkan mẹ́ta tó lè túbọ̀ mú wa sún mọ́ Ọlọ́run àti láti yí ayé wa padà fún rere. Ṣé o ṣetán fún àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run tí yóò yí ohun gbogbo padà?

More

A fé láti dúpe lowo David C Cook fún ipese ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí, Jọ̀ọ́ bè eyii wò: http://www.dccpromo.com/aha/