Ìjọba DéÀpẹrẹ
ÀDÚRÀ:
Ọlọ́run, ẹ ṣeun tí ẹ fún mi ní ìdánimọ̀ titun gẹ́gẹ́bí ọmọ yín. Kọ́ mi ní ohun tí èyí túmọ̀ sí lónìí.
IBI KÍKÀ:
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò ìgbàgbọ́ wọn nítorí wọ́n ń ní ìrírí ìbànújẹ́ àti ọgbẹ́ ọkàn fún àwọn ìhùwàsí àti ìpinnu àtẹ̀yìnwá. Ní ìpòǹgbẹ fún ìyípadà, wọ́n máa wá ìjọ kan lọ tàbí darapọ̀ mọ́ ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn. Kò sí ohun tó burú nípa ìpòǹgbẹ fún ìyípadà. Kódà, ìfẹ́ Ọlọ́run gan-an fún ọ nìyẹn.
Àmọ́ bí òun ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ètò ìyípadà a máa yàtọ̀ sí tiwa lọ́pọ̀ ìgbà.
Ọ̀nà tó yára julọ sí ìyípadà ni a ma ń sábà fẹ́ tẹ̀lé, lẹ́yìnòrẹyìn a máa fi ìwà tí a fẹ́ yí padà ṣe àfojúsùn. Nípasẹ̀ ipá ara wa ni a má ń gbìyànjú láti yí padà. Èyí lè mú wa ní ìbànújẹ́ nípa ìjákulẹ̀ àti ìtìjú. Kíni ìdí? Nítorí ìṣòro wa pọ̀ jọjọ ju ìhùwàsí wa lọ.
Fi ojú inú wo ara rẹ níwájú domino ńlá kan, tí o sì rí wípé àtúbọ̀tán rẹ̀ kò ní dáa. O sálọ sí iwájú o sì gbìyànjú pẹ̀lú gbogbo ipá rẹ láti dá domino náà dúró kó má bì ṣubú. O ṣe àṣeyọrí láti múu dúró padà àmọ́ bí o ti yí'sẹ̀ padà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní yẹ̀ padà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni o ma ńṣe èyí léraléra, pẹ̀lú àṣeyọrí ní àwọn ìgbà kan àti ìjákulẹ̀ nígbà mìíràn. Àmọ́ àwọn ìṣẹ́gun náà kì í lọ títí. Nígbà náà ni ẹnìkan rọ̀ ọ́ láti fà kúrò nínú iṣẹ́ tó ń pin ni l'ẹ̀mí náà àti láti wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí àwọn ti ríi. Lọ́gán tí o bá sún sẹ́yìn, ó máa rọrùn láti rí domino náà láti ìhà tó yàtọ̀ àti wípé Ìwọ yóò wá ríi wípé domino náà ló ṣáájú lórí ilà domino gígùn tí a ti tò tẹ̀lé ara wọn, tí ọ̀kan yóò máa ṣubú lu òmíràn, títí tí yóò fi kan èyí tó kẹ́yìn. Ìhà titun yìí ma ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ríi wípé tí o bá ní ìpinnu tó dájú láti dá ìṣubú domino tó kẹ́yìn dúró, o ma ní láti sún sẹ́yìn.
Ọlọ́run mọ́ wípé gbogbo ìṣe sí wa ló ń ṣú yọ látinú ìdánimọ̀ wa. Fún ìdí èyí, ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ sí ibi ìyípadà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífún wa ní ìdánimọ̀ titun gẹ́gẹ́bí ọmọ Ọlọ́run, tí ó fẹ́ràn tí ó sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ìyípadà ojúlówó gbúdọ̀ bẹ̀rẹ̀ níbi ipele ìpìlẹ̀ ọkàn kí ó tó wá sú yọ nínú ìhùwàsí wa.
Níní ìmọ̀ wípé ìṣòro wa kọjá bí a ti ròó lọ a máa mú ìrẹ̀wẹ̀sì wá, àmọ́ ìwúrí ni fún wa láti mọ̀ wípé Ọlọ́run ń ṣíṣe lórí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wa. Ó ní ìpinnu láti parí ìyípadà tí ó ti bẹ̀rẹ̀ nínú wa.
ÀṢÀRÒ:
Wá àyè láti wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìdákẹ́-rọ́rọ́. Láìsí ìdíwọ́. Láìsí domino kankan. Ó ṣeé ṣeé kó gbà ọ́ ní àkókò díẹ̀ láti kọ́ bí a ti ń wà ní ìdákẹ́-rọ́rọ́ níwájú rẹ̀. Ní sùúrù; forí tì í síbẹ̀. Bí o ti ń fara balẹ̀ nínú ìparọ́rọ́ náà, tọrọ fún ìrírí tó jinlẹ̀ nípa ìwàláàyè rẹ̀. Bèrè àwọn ìhà ọkàn rẹ tí ó fẹ́ ṣíṣe lé lórí àti èyí tí ó fẹ́ sọ dọ̀tun.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.
More