Ìjọba DéÀpẹrẹ
ÀDÚRÀ:
Ọlọ́run, la ojú mi lónìí láti rí ara mi bí o ti rí mi.
FÚN KÍKÀ:
Ìdánímọ̀n wa ni ìtàn tí a sọ fún ara wa nípa ara wa. Ìtàn yẹn Jẹ́ àpẹrẹ jákèjádò àwọn ìgbésí ayé wa nípasẹ̀ àwọn ìbátan àti àwọn ìrírí pàtàkì wa. Ó Jẹ́ dígí nípasẹ̀ èyítí a wo àgbáyé. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kò mọ̀ nípa rẹ̀, síbẹ̀ ó ń darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpinnu àti ìwà wa sí àwọn ènìyàn àti ìṣẹ̀lẹ̀.
Fún àpẹẹrẹ, tí ó bá jé pé ní ìgbà kan ní àkókò tí ó ti kọjá o ti gbèrò nínú ọkàn rẹ pé o jẹ́ eni tí kò le ní fẹ̀, ó ṣé se láti rii ìjákulè ní àyíká rẹ. Tàbí, tí ìtàn rẹ bá sọ pé o níye lórí nìkan nígbàtí o bá ṣàṣeyọrí, nípa èyí o le wo ìgbésí ayé rẹ bí ìdíje, èyí tí ó le mú kí ìhùwàsí rẹ kí ó ma lọ sí òkè àti ìsàlè tí ó dá lórí àṣeyọrí tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ní.
Àwọn ìtàn wọ̀nyí, tàbí àwọn ìtàn-àlàyé, jẹ́ ìyàlẹ́nu tí ó lágbára àti pé o lé ṣe àpẹrẹ púpò jùlọ sí ìgbésí ayé wa. Ọlọ́run mọn èyí nípa wa. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ó mú ìyípadà wá ni nípa rí rọ́pò ìtàn àtijó wa pẹ̀lú tuntun.
Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàpèjúwe ìtàn tuntun kan tó ṣàlàyé ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Ó sọ ọ̀nà tuntun kan láti fi wo ara wọn—bí Ọlọ́run ṣe ń wo wọn. Pọ́ọ̀lù rìn nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wọn. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nísinsìnyí nípa wọn nítorí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe. Àti pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí Jẹ́ òtító fún àwa pàápàá. Wọ́n Jẹ́ òtító laibikita boya wọn lérò pé kò jẹ́ òtító. Wọ́n jẹ́ òtító pàápàá ti o kò bá ṣe ńkankan láti jogún wọn. Òótọ́ ni wọ́n jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ti sọ bẹ́ẹ̀.
ÀKÍYÈSÍ:
Gba àkókò díè láti ko gbogbo àwọn ohun tí ẹṣẹ ọ̀rọ̀ yìí sọ nípa rẹ tí ó jẹ́ òtító gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù. Máse yá ra kaa, ṣùgbọ́n fi ara balẹ̀ láti lóye ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ. Àwọn òtítọ́ ọ̀kan tàbí méjì wòó ni ó fà sí ọkàn rẹ?. Àwọn òtító wo ni o fẹ́ràn làti mọn ìjìnlẹ̀?. Kọ àwọn wọ̀nyí sórí ìwé alá lèpọ̀ tàbí káàdì atọ́ka kí o sì fi sí ibìkan tí o lè rii lọ́joojúmọ́
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.
More