Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 9 nínú 15

ÀDÚRÀ:

Ọlọ́run, ràn mí lọ́wọ́ láti rí bí O ṣe ńṣiṣẹ́ nínú mi lónìí.


Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ:

Lákọ̀kọ́, àwọn ẹsẹ yìí lè rújú. Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ńsọ nipé ìgbàlà jẹ́ ohun tí a lè ṣiṣẹ́ kàn, ohun tí ó jẹ́ pé a ní láti "ṣiṣẹ́ fún?" A mọ̀ láti inú ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé-mímọ́ míràn pé ìgbàlà kìí ṣe ohun tí a lè ṣiṣẹ́ fún; ó jẹ́ ohun tí a rí gbà. Ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ ni tí a fi fún wa làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorínáà, kíni ohun tí Pọ́ọ̀lù ńtọ́ka sí níbí?


Kọ́kọ́rọ́ tó lè jẹ kí a ní òye ọ̀rọ̀ yìí "ṣiṣẹ́ ìgbàlà rẹ" ni a rí ní ẹsẹ tó tẹ̀lé e níbití Pọ́ọ̀lù ti kọ ọ́ pé, "Ọlọ́run ní ńṣiṣẹ́ nínú yín." Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn atẹ̀lé Jésù yìí láti tẹ̀síwájú nínú ìdàgbàsókè ẹ̀mí wọn. Títẹ̀lé Jésù kìí ṣe ìpinnu àyáraṣe lójú ẹsẹ̀. Ó jẹ́ onírúurú àkókò àti ìpinnu tó parapọ̀ láti di ìrìn-àjò ìyípadà. Ní àkókò tí a kọ́ ṣe ìpinnu láti tẹ̀lé Jésù, Ọlọ́run kéde rẹ̀ pé o jẹ́ aláìlábàwọ́n àti olòtìtọ́ lójú Rẹ̀. Ó fún ọ ní àpèlé àti ipò titun gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run. Ohun tí à ń pe eléyìí nínú ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Bíbélì ni ìdáláre. Ìpèlè tó kù nínú ìrìn-àjò náà ni ìgbésẹ̀ tí a ó gbé láti gbà jẹ́ ohun tí Ọlọ́run tí pàṣẹ rẹ̀ pé kí a jẹ́. Èyí ni ìsọdimímọ́. Ọlọ́run ti f'arajìn fún ìgbésẹ̀ yìí nínú ayé rẹ. Ó ń ṣisẹ́ "nínú rẹ láti fẹ́ àti láti ṣe ohun tí yíó mú ìfẹ́ inú rere Rẹ ṣẹ.” Ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe ohun tí yíò ṣe láìsí ipa tìrẹ níbẹ̀.


Ajínhìnrere George Müller sọ ọ́ báyìí pé: “Onígbàgbọ́ gbọdọ̀ parí, gbọdọ̀ mú wá sí òpin, gbọdọ̀ ṣe àmúlò dé ojú òṣùwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ti fi fún wa bí àlàkalẹ̀... Ó ní láti ṣisẹ́ ohun ti Ọlọ́run nínú oore-ọ̀fẹ́ fúnraarẹ̀ ti ṣisẹ́ nínú rẹ̀.”


Èyí ni ohun tí ìrìn-àjò ẹ̀mí túmọ̀ sí—ṣiṣe iṣẹ́ ohun nínú ohun tí Ọlọ́run ńṣe. A jẹ́ alábàṣiṣẹ́pọ̀ Ọlọ́run nínú iṣẹ́ ìyípadà tí Ó ńṣe nínú ayé.


ÀṢÀRÒ:

Wá ibi tí ó dákẹ́ rọ́rọ́ kan kí o sì f'arabalẹ̀ wà pẹ̀lú Ọlọ́run níbẹ̀. O lè ní láti jà fún un, ṣùgbọ́n mọ̀ọ́mọ̀ wá ibi tí ó jẹ́ pé wà á ti wà ní ìdákẹ́rọ́rọ́ pátápátá.

Bèèrè pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí o mọ ìwàálàyè Rẹ̀ sí í. Bèèrè pé kí Ó yànnàná bí Ó ṣe ń ṣisẹ́ nínú rẹ àti bí o ṣe lè kó ipa takun-takun nínú ìdàgbàsókè ẹ̀mí rẹ. Lákòtán, dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ fún jíjẹ́ olótìtọ́ Rẹ̀, kí o sì bèèrè pé kí Ó mú kí òye ẹ̀mí Rẹ̀ tí ń ṣisẹ́ nínú rẹ múná d'óko sí i.


Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 8Ọjọ́ 10

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org