Ìjọba DéÀpẹrẹ

Kingdom Come

Ọjọ́ 13 nínú 15

ÀDÚRÀ:

Ọlọ́run, mo fẹ́ bùkún àwọn ẹlòmíràn nítorípé O ti bùkún mi. Fi hàn mí bí mo ṣe lè ṣe èyí lónìí kí O sì fún mi ní ìgboyà láti ṣeé l'áṣepé.


Ẹ̀KỌ́ KÍKÀ:

Wòye rẹ̀ pé ò ń ṣe àyíkiri àwọn ìròyìn lórí ìkànnì ìbánidọ̀rẹ́ rẹ, o sì wá ṣe alábàpàdé ìròyìn kan tí ó ru ọ́ sókè. Ó tọ́ka sí ǹkankan tí kò tọ̀nà nínû ayé, ọkàn rẹ sì jí gìrì láti dá síi àti láti wá ǹkan ṣe síi. Nítorínáà, o fi ìròyìn yìí ṣ'ọwọ́ sí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú àfikún ọ̀rọ̀ tìrẹ díẹ̀ lórí bí ó ti bà ọ̀ l'ọ́kàn jẹ́ tó pé kò sí ẹnìkan tí ó tara tó láti ṣe ǹkan síi. Lẹhìn náà… ò ń bá ìgbé ayé rẹ lọ pẹ̀lú ìdùnnú ọkàn pé ìwọ náà dá síi. Óò lọ sí ibìkankan. Oò ní àjọrò gidi pẹ̀lú ẹnìkankan. Oò tilẹ̀ mú ǹkankan ṣe ní pàtó. Ṣùgbọ́n ó ṣe ọ́ bíi ẹnipé o ṣe bẹ́ẹ̀.


Ṣe èyí jẹ mọ́ ọ? Irú ìjíròrò báyìí ní orúkọ tí wọ́n ń pèé. Òun ni "ìwà ọ̀lẹ" ọ̀rọ̀ yìí sì wà nínú ìwé-ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó jẹ́ ọ̀nà àbùjá—àti ọ̀nà àkékúrú—sí ìpòǹgbẹ wa láti sọ ayé di ibi tí ó dára jù bí ó ti wà lọ. Èyí kò sọ pé fífi àwọn èròǹgbà pàtàkì ṣ'ọwọ́ sí ẹlòmíràn kò ní àǹfààní tirẹ̀. Ṣùgbọ́n pínpín ìròyìn báyìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kan nínú ìrìn-àjò tó tóbi gan an. Bí a bá sí dẹ́kun ìpòǹgbẹ wa láti tara bọ̀ ọ́ kí ó tóó di pé a dé ààrin gbùngbùn rẹ̀ gan an, a jẹ́ pé a ó pàdánù ọ̀kan pàtàkì nínú ohun tí Ọlọrun fẹ́ ṣe nínú àti nípasẹ̀ wa. Èyí yíó wá dàbíi pé a lọ s'ílé oúnjẹ aláfẹ́ ńlá, a sì ń kó ìpékeré jẹ kí oúnjẹ gidi tóó dé'lẹ̀. A kàn pàdánù ohun tí ó wù wá láti jẹ gan an nìyẹn.


Ọlọ́run ń pè wà pé kí a ju "oníwà ọ̀lẹ" lọ. Ní àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a kọ s'ókè, láti inú ìwé Gẹ́nẹ́sìsì, a sọ fún Àbrámù (ẹni tí a ó padà sọ di Ábráhámù) pé Ọlọ́run yíó bùkún fún un, ṣùgbọ́n lójú ẹsẹ̀ Ọlọ́run tètè sọ fún un pé "yíó jẹ́ ìbùkún.” Èyí jẹ́ ẹ̀bùn tí o sopọ̀ mọ́ èrèdí kan. Ọlọ́run bùkún fún Àbrámù, kí òun náà baà lè bùkún àwọn ẹlòmíràn.


Kókó tó so gbogbo Májẹ̀mú Tuntun pọ̀ náà nìyìí. Pọ́ọ̀lù na'wọ́ gán kókó yìí ní 2 Kọ́ríntì 1:3–7. Ó kọ ọ́ pé Ọlọ́run mú ìtùnú wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ díẹ̀, kí àwa náà baà lè tu ẹlòmíràn nínú. Ó jọ bí ẹnipé nínú àṣà wa, a lè fẹ́ẹ́ tún ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù kọ, bí ẹni pé ohun tí ó ń sọ ni pé, “Ọlọ́run ti tù ọ́ nínú kí o baà lè fi ìròyìn ráńṣè lóri bí àwọn ènìyàn ṣe pọ̀ láyé tí wọ́n níílò ìtùnú, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí kò k'ọbiara síi mọ̀ pé o rò pé ènìyàn burúkú niwọ́n.”


Má ṣubú sínú ẹ̀tàn yí o. Kò tó kí o kàn "tún ìròyìn fi ṣ'ọwọ́" lòrì i bí ẹnìkán ṣe gba'rata lórí ohun tí kò tọ́. Ọlọ́run pè wá kí a jẹ́ ara ojútùú, èyí tí ó le tí ó sì nira ṣùgbọ́n ó ní èrè nínú jọjọ.


Bí o bá ti fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Ọlọ́run tí kò lọ́ra láti t'ara bọ iṣẹ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí làti wá ọ rí, nítorínáà ó yẹ kí á bèèrè ohun kannáà lọ́wọ́ wa kí á lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.


Nípasẹ̀ Jésù, Ọlọ́run tí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìbùkún wà fún wa, ṣùgbọ́n Ó tún fún wa ní ìpè àti èrèdí—làti bùkún fún ayé. A ti pè wá láti fi tinútinú fi àkókò, ohun ìní àti agbára wa jì láti darapọ̀ mọ́ Ọlọ́run láti mú ìwòsàn àti ìsọdọtún wá sí ayé tó ti rún wógówógó yìí. A bùkún wa láti bùkúnni a sì yí wà padà láti mú ìyípadà wá.


ÀṢÀRÒ:

Ó ṣeéṣe kí ayé rẹ nìkan jẹ́ iṣẹ́ ìránṣé ààyè nípa Jésù tí ẹnìkan yíó gbọ́. Kíni ayé rẹ ń sọ nípa ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ọ? Kíni ayé rẹ ń sọ nípa ohun tí ó ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run?


Lo àsìkò díẹ̀ lónìí láti ṣe àkọsílẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè òkè yìí. Kíni ohun tí ó ṣe pàtàkì sí ọ? Bèèrè pé kí Ọlọrun fi àwọn apá ibìkan nínú ọkàn rẹ hàn ọ́ tí kò jẹ́ kí ayé rẹ fi ohun tí o k'áràmásìkí rẹ̀ hàn.


Ọjọ́ 12Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

Kingdom Come

A tí gbọ́ pé Jésù ń fún ni ní "ìyè l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́" àwa náà sì fẹ́ irú ìrírí yìí. A fẹ́ irú ìgbé-ayé tó wà l'ódìkejì ìyípadà. Ṣùgbọ́n irú ìyípadà wo ni a níílò? Àti pé bàwo ni a ó ṣe gbé ìgbésẹ́ ìyípadà náà? Nínú Ìjọba Dé ìwọ yíó ṣe àgbéyẹ̀wo ọ̀nà tuntun láti gbé ìgbé ayé àtoríkòdì tí Ọlọ́run pè wá sí.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Àwùjọ North Point fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí http://northpoint.org